Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 2:15-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Nigbati Farao si gbọ́ ọ̀ran yi, o nwá ọ̀na lati pa Mose. Ṣugbọn Mose sá kuro niwaju Farao, o si ngbé ilẹ Midiani: o si joko li ẹba kanga kan.

16. Njẹ alufa Midiani li ọmọbinrin meje, nwọn si wá, nwọn pọn omi, nwọn si kún ọkọ̀ imumi lati fi omi fun agbo-ẹran baba wọn.

17. Awọn oluṣọ-agutan si wá, nwọn si lé wọn kuro: nigbana ni Mose dide duro, o ràn wọn lọwọ, o si fi omi fun agbo-ẹran wọn.

18. Nigbati nwọn si padà dé lati ọdọ Reueli baba wọn, o ni Ẽtiri ti ẹnyin fi tète dé bẹ̃ loni?

19. Nwọn si wipe, Ara Egipti kan li o gbà wa lọwọ awọn oluṣọ-agutan, o si pọn omi to fun wa pẹlu, o si fi fun agbo-ẹran.

20. O si wi fun awọn ọmọbinrin rẹ̀ pe Nibo li o gbé wà? ẽṣe ti ẹnyin fi ọkunrin na silẹ? ẹ pè e ki o le wá ijẹun.

21. O si dùn mọ́ Mose lati ma bá ọkunrin na gbé: on si fi Sippora ọmọbinrin rẹ̀ fun Mose.

22. On si bi ọmọkunrin kan fun u, o si sọ orukọ rẹ̀ ni Gerṣomu: nitoriti o wipe, Emi ti nṣe atipo ni ilẹ ajeji.

23. O si ṣe lẹhin ọjọ́ pupọ̀, ti ọba Egipti kú: awọn ọmọ Israeli si ngbin nitori ìsin na, nwọn si ke, igbe wọn si goke tọ̀ Ọlọrun lọ nitori ìsin wọn.

24. Ọlọrun si gbọ́ irora wọn, Ọlọrun si ranti majẹmu rẹ̀ pẹlu Abrahamu, pẹlu Isaaki, ati pẹlu Jakobu.

25. Ọlọrun si bojuwò awọn ọmọ Israeli, Ọlọrun si mọ̀ ọ fun wọn.

Ka pipe ipin Eks 2