Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 18:22-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Ki nwọn ki o si ma ṣe idajọ awọn enia nigbakugba: yio si ṣe, gbogbo ẹjọ́ nla ni ki nwọn ki o ma mú tọ̀ ọ wá, ṣugbọn gbogbo ẹjọ́ kekeké ni ki nwọn ki o ma dá: yio si rọrùn fun iwọ tikalarẹ, nwọn o si ma bá ọ rù ẹrù na.

23. Bi iwọ ba jẹ ṣe nkan yi, bi Ọlọrun ba si fi aṣẹ fun ọ bẹ̃, njẹ iwọ o le duro pẹ, ati gbogbo awọn enia yi pẹlu ni yio si dé ipò wọn li alafia.

24. Mose si gbà ohùn ana rẹ̀ gbọ́, o si ṣe ohun gbogbo ti o wi.

25. Mose si yàn awọn enia ti o to ninu gbogbo Israeli, o si fi wọn ṣe olori awọn enia, olori ẹgbẹgbẹrun, olori ọrọrún, olori arãdọta, olori mẹwamẹwa.

26. Nwọn si nṣe idajọ awọn enia nigbakugba: ọ̀ran ti o ṣoro, nwọn a mútọ̀ Mose wá, ṣugbọn awọn tikalawọn ṣe idajọ gbogbo ọ̀ran kekeké.

27. Mose si jẹ ki ana rẹ̀ ki o lọ; on si ba tirẹ̀ lọ si ilẹ rẹ̀.

Ka pipe ipin Eks 18