Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 16:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NWỌN si ṣí lati Elimu, gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli si dé ijù Sini, ti o wà li agbedemeji Elimu on Sinai, ni ijọ́ kẹdogun oṣù keji, lẹhin igbati nwọn jade kuro ni ilẹ Egipti.

2. Gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli si nkùn si Mose ati si Aaroni ni ijù na:

3. Awọn ọmọ Israeli si wi fun wọn pe, Awa iba ti ti ọwọ́ OLUWA kú ni Egipti, nigbati awa joko tì ìkoko ẹran, ti awa njẹ ajẹyo; ẹnyin sá mú wa jade wá si ijù yi, lati fi ebi pa gbogbo ijọ yi.

4. Nigbana li OLUWA sọ fun Mose pe, Kiyesi i, emi o rọ̀jo onjẹ fun nyin lati ọrun wá; awọn enia yio si ma jade lọ ikó ìwọn ti õjọ li ojojumọ́, ki emi ki o le dan wọn wò, bi nwọn o fẹ́ lati ma rìn nipa ofin mi, bi bẹ̃kọ.

5. Yio si ṣe, li ọjọ́ kẹfa, nwọn o si pèse eyiti nwọn múwa; yio si to ìwọn meji eyiti nwọn ima kó li ojojumọ́.

6. Mose ati Aaroni si wi fun gbogbo awọn ọmọ Israeli pe, Li aṣalẹ, li ẹnyin o si mọ̀ pe, OLUWA li o mú nyin jade lati Egipti wá:

7. Ati li owurọ̀ li ẹnyin o si ri ogo OLUWA; nitoriti o gbọ́ kikùn nyin si OLUWA: ta si li awa, ti ẹnyin nkùn si wa?

Ka pipe ipin Eks 16