Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 12:9-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Ẹ máṣe jẹ ninu rẹ̀ ni tutù, tabi ti a fi omi bọ̀, bikoṣepe sisun ninu iná; ati ori rẹ̀, ati itan rẹ̀, ati akopọ̀ inu rẹ̀ pẹlu.

10. Ẹ kò si gbọdọ jẹ ki nkan ki o kù silẹ ninu rẹ̀ dé ojumọ́; eyiti o ba si kù di ijọ́ keji on ni ki ẹnyin ki o daná sun.

11. Bayi li ẹnyin o si jẹ ẹ; ti ẹnyin ti àmure didì li ẹgbẹ nyin, bàta nyin li ẹsẹ̀ nyin, ati ọpá nyin li ọwọ́ nyin, ẹnyin o si yara jẹ ẹ: irekọja OLUWA ni.

12. Nitoriti emi o là ilẹ Egipti já li oru na, emi o si kọlù gbogbo awọn akọ́bi ni ilẹ Egipti, ti enia ati ti ẹran; ati lara gbogbo oriṣa Egipti li emi o ṣe idajọ: emi li OLUWA.

13. Ẹ̀jẹ na ni yio si ṣe àmi fun nyin lara ile ti ẹnyin gbé wà: nigbati emi ba ri ẹ̀jẹ na, emi o ré nyin kọja, iyọnu na ki yio wá sori nyin lati run nyin nigbati mo ba kọlù ilẹ Egipti.

14. Ọjọ́ oni ni yio si ma ṣe ọjọ́ iranti fun nyin, ẹnyin o si ma ṣe e li ajọ fun OLUWA ni iran-iran nyin, ẹ o si ma ṣe e li ajọ nipa ìlana lailai.

15. Ijọ́ meje li ẹ o fi ma jẹ àkara alaiwu; li ọjọ́ kini gan li ẹ o palẹ iwukàra mọ́ kuro ni ile nyin; nitori ẹniti o ba jẹ àkara wiwu lati ọjọ́ kini lọ titi o fi di ọjọ́ keje, ọkàn na li a o ke kuro ninu Israeli.

16. Ati li ọjọ́ kini ki apejọ mimọ́ ki o wà, ati li ọjọ́ keje apejọ mimọ́ yio wà fun nyin; a ki yio ṣe iṣẹkiṣẹ ninu wọn, bikoṣe eyiti olukuluku yio jẹ, kìki eyinì li a le ṣe ninu nyin.

17. Ẹ o si kiyesi ajọ aiwukàra; nitori li ọjọ́ na gan ni mo mú ogun nyin jade kuro ni ilẹ Egipti; nitorina ni ki ẹ ma kiyesi ọjọ́ na ni iran-iran nyin nipa ìlana lailai.

18. Li oṣù kini li ọjọ kẹrinla oṣù na li aṣalẹ li ẹ o jẹ àkara alaiwu, titi yio fi di ọjọ́ kọkanlelogun oṣù na li aṣalẹ.

19. Ni ọjọ́ meje ni ki a máṣe ri iwukàra ninu ile nyin: nitori ẹniti o ba jẹ eyiti a wu, ọkàn na li a o ke kuro ninu ijọ Israeli, iba ṣe alejò, tabi ẹniti a bi ni ilẹ na.

20. Ẹ kò gbọdọ jẹ ohunkohun ti a wu; ninu ibugbé nyin gbogbo li ẹnyin o jẹ àkara alaiwu.

21. Nigbana ni Mose pè gbogbo awọn àgba Israeli, o si wi fun wọn pe, Ẹ jade lọ imú ọdọ-agutan fun ara nyin, gẹgẹ bi idile nyin, ki ẹ si pa irekọja na.

22. Ẹnyin o si mú ìdi ewe-hissopu, ẹ o si fi bọ̀ ẹ̀jẹ ti o wà ninu awokoto, ẹ o si fi ẹ̀jẹ na ti o wà ninu awokoto kùn ara atẹrigba, ati opó ìha mejeji; ẹnikẹni ninu nyin kò si gbọdọ jade lati ẹnu-ọ̀na ile rẹ̀ titi yio fi di owurọ̀.

23. Nitoriti OLUWA yio kọja lati kọlù awọn ara Egipti; nigbati o ba si ri ẹ̀jẹ lara atẹrigba, ati lara opó ìha mejeji, OLUWA yio si rekọja ẹnu-ọ̀na na, ki yio jẹ ki apanirun ki o wọle nyin wá lati kọlù nyin.

Ka pipe ipin Eks 12