Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 10:18-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. On si jade kuro niwaju Farao, o si bẹ̀ OLUWA.

19. OLUWA si yi afẹfẹ ìwọ-õrùn lile-lile ti o si fẹ́ awọn eṣú na kuro, o si gbá wọn lọ sinu Okun Pupa; kò si kù eṣú kanṣoṣo ni gbogbo ẹkùn Egipti.

20. Ṣugbọn OLUWA mu àiya Farao le, bẹ̃ni kò si jẹ ki awọn ọmọ Israeli ki o lọ.

21. OLUWA si wi fun Mose pe, Nà ọwọ́ rẹ si ọrun, ki òkunkun ki o ṣú yiká ilẹ Egipti, ani òkunkun ti a le fọwọbà.

22. Mose si nà ọwọ́ rẹ̀ si ọrun; òkunkun biribiri si ṣú ni gbogbo ilẹ Egipti ni ijọ́ mẹta:

23. Nwọn kò ri ara wọn, bẹ̃li ẹnikan kò si dide ni ipò tirẹ̀ ni ijọ́ mẹta: ṣugbọn gbogbo awọn ọmọ Israeli li o ni imọle ni ibugbé wọn.

24. Farao si pè Mose, o si wipe, Ẹ ma lọ, ẹ sìn OLUWA; kìki agbo ati ọwọ́-ẹran nyin ni ki o kù lẹhin; ki awọn ewe nyin ki o bá nyin lọ pẹlu.

25. Mose si wipe, Iwọ kò le ṣaima fun wa li ohun ẹbọ pẹlu ati ẹbọ sisun, ti awa o fi rubọ si OLUWA Ọlọrun wa.

26. Ẹran-ọ̀sin wa yio si bá wa lọ pẹlu; a ki yio fi ibósẹ-ẹran kan silẹ lẹhin; nitori ninu rẹ̀ li awa o mú sìn OLUWA Ọlọrun wa; awa kò si mọ̀ ohun na ti a o fi sìn OLUWA, titi awa o fi dé ibẹ̀.

27. Ṣugbọn OLUWA mu àiya Farao le, kò si fẹ́ jẹ ki nwọn lọ.

28. Farao si wi fun u pe, Kuro lọdọ mi, ma ṣọ́ ara rẹ, máṣe tun ri oju mi mọ́; nitori ni ijọ́ na ti iwọ ba ri oju mi iwọ o kú.

29. Mose si wipe, Iwọ fọ̀ rere; emi ki yio tun ri oju rẹ mọ́.

Ka pipe ipin Eks 10