Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹk. Jer 2:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. BAWO li Oluwa ti fi awọsanma bo ọmọbinrin Sioni ni ibinu rẹ̀! ti o sọ ẹwa Israeli kalẹ lati oke ọrun wá si ilẹ, ti kò si ranti apoti-itisẹ rẹ̀ li ọjọ ibinu rẹ̀!

2. Oluwa ti gbe gbogbo ibugbe Jakobu mì, kò si da a si: o ti wó ilu-odi ọmọbinrin Juda lulẹ, ninu irunu rẹ̀ o ti lù wọn bolẹ: o ti sọ ijọba na ati awọn ijoye rẹ̀ di alaimọ́.

3. O ti ke gbogbo iwo Israeli kuro ninu ibinu gbigbona rẹ̀: o ti fà ọwọ ọtun rẹ̀ sẹhin niwaju ọta, o si jo gẹgẹ bi ọwọ iná ninu Jakobu ti o jẹrun yikakiri.

4. O ti fà ọrun rẹ̀ gẹgẹ bi ọta: o duro, o mura ọwọ ọtun rẹ̀ gẹgẹ bi aninilara, o si pa gbogbo ohun didara ti oju fẹ iri ni agọ ọmọbinrin Sioni, o dà irunu rẹ̀ jade bi iná.

5. Oluwa jẹ gẹgẹ bi ọta: o ti gbe Israeli mì, o ti gbe gbogbo ãfin rẹ̀ mì: o ti pa ilu olodi rẹ̀ run o si ti fi ibanujẹ lori ibanujẹ fun ọmọbinrin Juda.

6. O si ti wó ọgba rẹ̀ lulẹ, gẹgẹ bi àgbala: o ti pa ibi apejọ rẹ̀ run: Oluwa ti mu ki a gbagbe ajọ-mimọ́ ati ọjọ isimi ni Sioni, o ti fi ẹ̀gan kọ̀ ọba ati alufa silẹ ninu ikannu ibinu rẹ̀.

7. Oluwa ti ṣá pẹpẹ rẹ̀ tì, o ti korira ibi-mimọ́ rẹ̀, o ti fi ogiri ãfin rẹ̀ le ọwọ ọta; nwọn ti pa ariwo ninu ile Oluwa, gẹgẹ bi li ọjọ ajọ-mimọ́.

8. Oluwa ti rò lati pa odi ọmọbinrin Sioni run: o ti nà okùn ìwọn jade, on kò ti ifa ọwọ rẹ̀ sẹhin kuro ninu ipanirun: bẹ̃ni o ṣe ki ile-iṣọ rẹ̀ ati odi rẹ̀ ki o ṣọ̀fọ; nwọn jumọ rẹ̀ silẹ.

9. Ẹnu-bode rẹ̀ wọnni rì si ilẹ; o ti parun o si ṣẹ́ ọpá idabu rẹ̀; ọba rẹ̀ ati awọn ijoye rẹ̀ wà lãrin awọn orilẹ-ède: ofin kò si mọ; awọn woli rẹ̀ pẹlu kò ri iran lati ọdọ Oluwa.

10. Awọn àgbagba ọmọbinrin Sioni joko ni ilẹ, nwọn dakẹ: nwọn ti ku ekuru sori wọn; nwọn ti fi aṣọ-ọ̀fọ di ara wọn: awọn wundia Jerusalemu sọ ori wọn kọ́ si ilẹ.

11. Oju mi gbẹ tan fun omije, inu mi nho, a dà ẹ̀dọ mi sori ilẹ, nitori iparun ọmọbinrin awọn enia mi: nitoripe awọn ọmọ wẹ̃rẹ ati awọn ọmọ-ọmu nkulọ ni ita ilu na.

12. Nwọn nsọ fun iya wọn pe, Nibo ni ọka ati ọti-waini gbe wà? nigbati nwọn daku gẹgẹ bi awọn ti a ṣalọgbẹ ni ita ilu na, nigbati ọkàn wọn dà jade li aiya iya wọn.

Ka pipe ipin Ẹk. Jer 2