Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹk. Jer 1:8-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Jerusalemu ti da ẹ̀ṣẹ gidigidi, nitorina li o ṣe di ẹni-irira: gbogbo awọn ti mbu ọla fun u kẹgan rẹ̀, nitoripe nwọn ri ihoho rẹ̀: lõtọ on kẹdùn, o si yi ẹ̀hin pada.

9. Ẽri rẹ̀ wà ni iṣẹti aṣọ rẹ̀; on kò si ranti opin rẹ̀ ikẹhin; nitorina ni o ṣe sọkalẹ ni isọkalẹ iyanu: kò ni olutunu, Oluwa, wò ipọnju mi, nitori ọta ti bori!

10. Aninilara ti nà ọwọ rẹ̀ jade sori gbogbo ohun daradara rẹ̀: nitori on ti ri pe awọn orilẹ-ède wọ ibi-mimọ́ rẹ̀, eyiti iwọ paṣẹ pe, nwọn kì o wọ inu ijọ tirẹ.

11. Gbogbo awọn enia rẹ̀ kẹdùn, nwọn wá onjẹ; nwọn fi ohun daradara fun onjẹ lati tu ara wọn ninu. Wò o, Oluwa, ki o si rò! nitori emi di ẹni-ẹ̀gan.

12. Kò ha kàn nyin bi, gbogbo ẹnyin ti nkọja? Wò o, ki ẹ si ri bi ibanujẹ kan ba wà bi ibanujẹ mi, ti a ṣe si mi! eyiti Oluwa fi pọn mi loju li ọjọ ibinu gbigbona rẹ̀.

13. Lati oke li a ti rán iná sinu egungun mi, o si ràn ninu rẹ̀: On ti nà àwọn fun ẹsẹ mi, o ti yi mi pada sẹhin; O ti mu mi dahoro, mo si rẹ̀wẹsi lojojumọ.

14. Okùn àjaga irekọja mi li a dimu li ọwọ rẹ̀; a so wọn pọ̀: nwọn yi ọrùn mi ka, nwọn tẹ agbara mi mọlẹ; Oluwa ti fi mi le ọwọ awọn ẹniti emi kò le dide si.

15. Oluwa ti tẹ̀ gbogbo awọn akọni mi mọlẹ labẹ ẹsẹ li arin mi: On ti pe apejọ sori mi lati tẹ̀ awọn ọdọmọkunrin mi rẹ́: Oluwa ti tẹ ifunti fun wundia, ọmọbinrin Juda.

16. Emi nsọkun nitori nkan wọnyi; oju mi! oju mi ṣàn omi silẹ, nitoripe olutunu ati ẹniti iba mu ọkàn mi sọji jina si mi: awọn ọmọ mi run, nitoripe ọta bori.

17. Sioni nà ọwọ rẹ̀ jade, kò si sí ẹnikan lati tù u ninu: Oluwa ti paṣẹ niti Jakobu pe, ki awọn aninilara rẹ̀ ki o yi i kakiri: Jerusalemu dabi obinrin ẹlẹgbin lãrin wọn.

18. Oluwa ṣe olododo; nitoriti emi ti ṣọ̀tẹ si aṣẹ ẹnu rẹ̀: gbọ́, (emi bẹ nyin,) gbogbo orilẹ-ède, ẹ si wò ikãnu mi; awọn wundia mi ati awọn ọdọmọkunrin mi lọ si igbekun.

19. Emi pè awọn olufẹ mi, awọn wọnyi tàn mi jẹ: awọn alufa mi, ati àgbagba mi jọwọ ẹmi wọn lọwọ ni ilu, nigbati nwọn nwá onjẹ wọn lati mu ẹmi wọn sọji.

20. Wò o, Oluwa: nitoriti emi wà ninu ipọnju: inu mi nhó; ọkàn mi yipada ninu mi; nitoriti emi ti ṣọ̀tẹ gidigidi: lode, idà sọni di alailọmọ, ni ile, o dabi ikú!

Ka pipe ipin Ẹk. Jer 1