orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹk. Jer 1 Yorùbá Bibeli (YCE)

Ìbànújẹ́ Jerusalẹmu

1. BAWO ni ilu ṣe joko nikan, eyi ti o ti kún fun enia! o wà bi opó! on ti iṣe ẹni-nla lãrin awọn orilẹ-ède! ọmọ-alade obinrin lãrin igberiko, on di ẹrú!

2. On sọkun gidigidi li oru, omije rẹ̀ si wà ni ẹ̀rẹkẹ rẹ̀: lãrin gbogbo awọn olufẹ rẹ̀, kò ni ẹnikẹni lati tù u ninu: gbogbo awọn ọrẹ rẹ̀ ti ba a lo ẹ̀tan, nwọn di ọta rẹ̀.

3. Juda lọ si àjo nitori ipọnju ati isin-ẹrú nla: o joko lãrin awọn orilẹ-ède, on kò ri isimi: gbogbo awọn ti nlepa rẹ̀ ba a ni ibi hiha.

4. Ọ̀na Sioni wọnni nṣọ̀fọ, nitori ẹnikan kò wá si ajọ-mimọ́: gbogbo ẹnu-bode rẹ̀ dahoro: awọn alufa rẹ̀ kẹdun, awọn wundia rẹ̀ nkãnu, on si wà ni kikoro ọkàn.

5. Awọn aninilara rẹ̀ bori, awọn ọta rẹ̀ ri rere: nitori Oluwa ti pọn ọ loju nitori ọ̀pọlọpọ irekọja rẹ̀; awọn ọmọ wẹrẹ rẹ̀ lọ si igbekun niwaju awọn aninilara.

6. Gbogbo ẹwà ọmọbinrin Sioni si ti lọ kuro lọdọ rẹ̀: awọn ijoye rẹ̀ dabi agbọnrin ti kò ri pápá oko tutu, nwọn si lọ laini agbara niwaju alepa nì,

7. Li ọjọ ipọnju rẹ̀ ati inilara rẹ̀ ni Jerusalemu ranti gbogbo ohun daradara ti o ti ni li ọjọ igbãni, nigbati awọn enia rẹ̀ ṣubu si ọwọ ọta, ẹnikan kò si ràn a lọwọ: awọn aninilara ri i, nwọn si fi iparun rẹ̀ ṣẹsin.

8. Jerusalemu ti da ẹ̀ṣẹ gidigidi, nitorina li o ṣe di ẹni-irira: gbogbo awọn ti mbu ọla fun u kẹgan rẹ̀, nitoripe nwọn ri ihoho rẹ̀: lõtọ on kẹdùn, o si yi ẹ̀hin pada.

9. Ẽri rẹ̀ wà ni iṣẹti aṣọ rẹ̀; on kò si ranti opin rẹ̀ ikẹhin; nitorina ni o ṣe sọkalẹ ni isọkalẹ iyanu: kò ni olutunu, Oluwa, wò ipọnju mi, nitori ọta ti bori!

10. Aninilara ti nà ọwọ rẹ̀ jade sori gbogbo ohun daradara rẹ̀: nitori on ti ri pe awọn orilẹ-ède wọ ibi-mimọ́ rẹ̀, eyiti iwọ paṣẹ pe, nwọn kì o wọ inu ijọ tirẹ.

11. Gbogbo awọn enia rẹ̀ kẹdùn, nwọn wá onjẹ; nwọn fi ohun daradara fun onjẹ lati tu ara wọn ninu. Wò o, Oluwa, ki o si rò! nitori emi di ẹni-ẹ̀gan.

12. Kò ha kàn nyin bi, gbogbo ẹnyin ti nkọja? Wò o, ki ẹ si ri bi ibanujẹ kan ba wà bi ibanujẹ mi, ti a ṣe si mi! eyiti Oluwa fi pọn mi loju li ọjọ ibinu gbigbona rẹ̀.

13. Lati oke li a ti rán iná sinu egungun mi, o si ràn ninu rẹ̀: On ti nà àwọn fun ẹsẹ mi, o ti yi mi pada sẹhin; O ti mu mi dahoro, mo si rẹ̀wẹsi lojojumọ.

14. Okùn àjaga irekọja mi li a dimu li ọwọ rẹ̀; a so wọn pọ̀: nwọn yi ọrùn mi ka, nwọn tẹ agbara mi mọlẹ; Oluwa ti fi mi le ọwọ awọn ẹniti emi kò le dide si.

15. Oluwa ti tẹ̀ gbogbo awọn akọni mi mọlẹ labẹ ẹsẹ li arin mi: On ti pe apejọ sori mi lati tẹ̀ awọn ọdọmọkunrin mi rẹ́: Oluwa ti tẹ ifunti fun wundia, ọmọbinrin Juda.

16. Emi nsọkun nitori nkan wọnyi; oju mi! oju mi ṣàn omi silẹ, nitoripe olutunu ati ẹniti iba mu ọkàn mi sọji jina si mi: awọn ọmọ mi run, nitoripe ọta bori.

17. Sioni nà ọwọ rẹ̀ jade, kò si sí ẹnikan lati tù u ninu: Oluwa ti paṣẹ niti Jakobu pe, ki awọn aninilara rẹ̀ ki o yi i kakiri: Jerusalemu dabi obinrin ẹlẹgbin lãrin wọn.

18. Oluwa ṣe olododo; nitoriti emi ti ṣọ̀tẹ si aṣẹ ẹnu rẹ̀: gbọ́, (emi bẹ nyin,) gbogbo orilẹ-ède, ẹ si wò ikãnu mi; awọn wundia mi ati awọn ọdọmọkunrin mi lọ si igbekun.

19. Emi pè awọn olufẹ mi, awọn wọnyi tàn mi jẹ: awọn alufa mi, ati àgbagba mi jọwọ ẹmi wọn lọwọ ni ilu, nigbati nwọn nwá onjẹ wọn lati mu ẹmi wọn sọji.

20. Wò o, Oluwa: nitoriti emi wà ninu ipọnju: inu mi nhó; ọkàn mi yipada ninu mi; nitoriti emi ti ṣọ̀tẹ gidigidi: lode, idà sọni di alailọmọ, ni ile, o dabi ikú!

21. Nwọn gbọ́ bi emi ti nkẹdùn to: sibẹ kò si olutunu fun mi: gbogbo awọn ọta mi gbọ́ iyọnu mi; inu wọn dùn nitori iwọ ti ṣe e: iwọ o mu ọjọ na wá ti iwọ ti dá, nwọn o si ri gẹgẹ bi emi.

22. Jẹ ki gbogbo ìwa-buburu wọn wá si iwaju rẹ; si ṣe si wọn, gẹgẹ bi iwọ ti ṣe si mi nitori gbogbo irekọja mi: nitori ikẹdùn mi pọ̀, ọkàn mi si rẹ̀wẹsi.