Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹk. Jer 1:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. BAWO ni ilu ṣe joko nikan, eyi ti o ti kún fun enia! o wà bi opó! on ti iṣe ẹni-nla lãrin awọn orilẹ-ède! ọmọ-alade obinrin lãrin igberiko, on di ẹrú!

2. On sọkun gidigidi li oru, omije rẹ̀ si wà ni ẹ̀rẹkẹ rẹ̀: lãrin gbogbo awọn olufẹ rẹ̀, kò ni ẹnikẹni lati tù u ninu: gbogbo awọn ọrẹ rẹ̀ ti ba a lo ẹ̀tan, nwọn di ọta rẹ̀.

3. Juda lọ si àjo nitori ipọnju ati isin-ẹrú nla: o joko lãrin awọn orilẹ-ède, on kò ri isimi: gbogbo awọn ti nlepa rẹ̀ ba a ni ibi hiha.

4. Ọ̀na Sioni wọnni nṣọ̀fọ, nitori ẹnikan kò wá si ajọ-mimọ́: gbogbo ẹnu-bode rẹ̀ dahoro: awọn alufa rẹ̀ kẹdun, awọn wundia rẹ̀ nkãnu, on si wà ni kikoro ọkàn.

5. Awọn aninilara rẹ̀ bori, awọn ọta rẹ̀ ri rere: nitori Oluwa ti pọn ọ loju nitori ọ̀pọlọpọ irekọja rẹ̀; awọn ọmọ wẹrẹ rẹ̀ lọ si igbekun niwaju awọn aninilara.

6. Gbogbo ẹwà ọmọbinrin Sioni si ti lọ kuro lọdọ rẹ̀: awọn ijoye rẹ̀ dabi agbọnrin ti kò ri pápá oko tutu, nwọn si lọ laini agbara niwaju alepa nì,

7. Li ọjọ ipọnju rẹ̀ ati inilara rẹ̀ ni Jerusalemu ranti gbogbo ohun daradara ti o ti ni li ọjọ igbãni, nigbati awọn enia rẹ̀ ṣubu si ọwọ ọta, ẹnikan kò si ràn a lọwọ: awọn aninilara ri i, nwọn si fi iparun rẹ̀ ṣẹsin.

8. Jerusalemu ti da ẹ̀ṣẹ gidigidi, nitorina li o ṣe di ẹni-irira: gbogbo awọn ti mbu ọla fun u kẹgan rẹ̀, nitoripe nwọn ri ihoho rẹ̀: lõtọ on kẹdùn, o si yi ẹ̀hin pada.

9. Ẽri rẹ̀ wà ni iṣẹti aṣọ rẹ̀; on kò si ranti opin rẹ̀ ikẹhin; nitorina ni o ṣe sọkalẹ ni isọkalẹ iyanu: kò ni olutunu, Oluwa, wò ipọnju mi, nitori ọta ti bori!

10. Aninilara ti nà ọwọ rẹ̀ jade sori gbogbo ohun daradara rẹ̀: nitori on ti ri pe awọn orilẹ-ède wọ ibi-mimọ́ rẹ̀, eyiti iwọ paṣẹ pe, nwọn kì o wọ inu ijọ tirẹ.

Ka pipe ipin Ẹk. Jer 1