Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dan 9:16-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo ododo rẹ, lõtọ, jẹ ki ibinu ati irunu rẹ yi kuro lori Jerusalemu, ilu rẹ, òke mimọ́ rẹ: nitori ẹ̀ṣẹ wa, ati ẹ̀ṣẹ awọn baba wa ni Jerusalemu, ati awọn enia rẹ fi di ẹ̀gan si gbogbo awọn ti o yi wa ka.

17. Njẹ nitorina, Ọlọrun wa, gbọ́ adura ọmọ-ọdọ rẹ, ati ẹ̀bẹ rẹ̀, ki o si mu ki oju rẹ ki o mọlẹ si ibi-mimọ́ rẹ ti o dahoro, nitori ti Oluwa.

18. Tẹ eti rẹ silẹ, Ọlọrun mi, ki o si gbọ́: ṣi oju rẹ, ki o si wò idahoro wa, ati ilu ti a nfi orukọ rẹ pè: nitoriti awa kò gbé ẹ̀bẹ wa kalẹ niwaju rẹ nitori ododo wa, ṣugbọn nitori ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ nla.

19. Oluwa, gbọ́, Oluwa, dariji: Oluwa, tẹ eti rẹ silẹ ki o si ṣe; máṣe jafara, nitori ti iwọ tikararẹ, Ọlọrun mi: nitori orukọ rẹ li a fi npè ilu rẹ, ati awọn enia rẹ.

20. Bi emi si ti nwi, ti emi ngbadura, ati bi emi si ti njẹwọ ẹṣẹ mi, ati ẹ̀ṣẹ Israeli awọn enia mi, ti emi si ngbé ẹbẹ mi kalẹ niwaju Oluwa, Ọlọrun mi, nitori òke mimọ́ Ọlọrun mi.

21. Bẹni, bi mo ti nwi lọwọ ninu adura mi, ọkunrin na, Gabrieli ti mo ti ri ni iran mi li atetekọṣe, li a mu lati fò wá kankan, o de ọdọ mi niwọn akokò ẹbọ aṣãlẹ.

22. O mu mi mọ̀, o si mba mi sọ̀rọ wipe, Danieli, mo jade wá nisisiyi lati fi oye fun ọ.

23. Ni ipilẹṣẹ ẹ̀bẹ rẹ li ọ̀rọ ti jade wá, emi si wá lati fi hàn fun ọ, nitoriti iwọ iṣe ayanfẹ gidigidi: nitorina, moye ọ̀ran na, ki o si kiyesi iran na.

24. Adọrin ọ̀sẹ li a pinnu sori awọn enia rẹ, ati sori ilu mimọ́ rẹ, lati ṣe ipari irekọja, ati lati fi edidi di ẹ̀ṣẹ, ati lati ṣe ilaja fun aiṣedẽde ati lati mu ododo ainipẹkun wá ati lati ṣe edidi iran ati woli, ati lati fi ororo yàn Ẹni-mimọ́ julọ nì.

25. Nitorina ki iwọ ki o mọ̀, ki o si ye ọ, pe lati ijade lọ ọ̀rọ na lati tun Jerusalemu ṣe, ati lati tun u kọ́, titi de igba ọmọ-alade Ẹni-ororo na, yio jẹ ọ̀sẹ meje, ati ọ̀sẹ mejilelọgọta: a o si tun igboro rẹ̀ ṣe, a o mọdi rẹ̀, ṣugbọn ni igba wahala.

26. Lẹhin ọ̀sẹ mejilelọgọta na li a o ke Ẹni-ororo na kuro, kì yio si si ẹnikan fun u, ati awọn enia ọmọ-alade kan ti yio wá ni yio pa ilu na ati ibi-mimọ́ run; opin ẹniti mbọ yio dabi ikún omi, ati ogun titi de opin, eyi ni ipari idahoro.

27. On o si fi idi majẹmu kan mulẹ fun ọ̀pọlọpọ niwọn ọ̀sẹ kan: ati lãrin ọ̀sẹ na ni yio mu ki a dẹkun ẹbọ, ati ọrẹ-ẹbọ, irira isọdahoro yio si duro lori ibi-mimọ́ titi idajọ ti a pinnu yio túdà sori asọnidahoro.

Ka pipe ipin Dan 9