Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dan 8:9-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Ati lati inu ọkan ninu wọn ni iwo kekere kan ti jade, ti o si di alagbara gidigidi, si iha gusu, ati si iha ila-õrùn, ati si iha ilẹ ogo.

10. O si di alagbara, titi de ogun ọrun, o si bì ṣubu ninu awọn ogun ọrun, ati ninu awọn irawọ si ilẹ, o si tẹ̀ wọn mọlẹ.

11. Ani o gbé ara rẹ̀ ga titi de ọdọ olori awọn ogun na pãpa, a si ti mu ẹbọ ojojumọ kuro lọdọ rẹ̀, a si wó ibujoko ìwa-mimọ́ rẹ̀ lulẹ.

12. A si fi ogun le e lọwọ pẹlu ẹbọ ojojumọ nitori irekọja, o si ja otitọ lulẹ, o si nṣe eyi, o si nri rere.

13. Mo si gbọ́ ẹni-mimọ́ ti nsọ̀rọ; ẹni-mimọ́ kan si wi fun ẹnikan ti nsọ̀rọ pe, Iran na niti ẹbọ ojojumọ, ati ti irekọja isọdahoro, ani lati fi ibi-mimọ́ ati ogun fun ni ni itẹmọlẹ yio ti pẹ to?

14. O si wi fun mi pe, titi fi di ọgbọnkanla le ọgọrun ti alẹ ti owurọ: nigbana ni a o si yà ibi-mimọ́ si mimọ́.

15. O si ṣe ti emi, ani emi Danieli si ti ri iran na, ti mo si nfẹ imọ̀ idi rẹ̀, si kiyesi i, ẹnikan duro niwaju mi, gẹgẹ bi aworan ọkunrin.

16. Emi si gbọ́ ohùn enia kan lãrin odò Ulai, ti o pè, ti o si wi pe, Gabrieli, mu ki eleyi moye iran na.

17. Bẹ̃li o si wá sibi ti mo duro: nigbati o si de, ẹ̀ru bà mi, mo si da oju mi bolẹ: ṣugbọn o wi fun mi pe, Kiyesi i, ọmọ enia: nitoripe ti akokò igba ikẹhin ni iran na iṣe.

Ka pipe ipin Dan 8