Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dan 7:4-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Ẹranko kini dabi kiniun, o si ni iyẹ-apa idì: mo si wò titi a fi fà iyẹ-apa rẹ̀ wọnni tu, a si gbé e soke kuro ni ilẹ, a mu ki o fi ẹsẹ duro bi enia, a si fi aiya enia fun u.

5. Sa si kiyesi, ẹranko miran, ekeji, ti o dabi ẹranko beari, o si gbé ara rẹ̀ soke li apakan, o si ni egungun-ìha mẹta lẹnu rẹ̀ larin ehin rẹ̀: nwọn si wi fun u bayi pe, Dide ki o si jẹ ẹran pipọ.

6. Lẹhin eyi, mo ri, si kiyesi i, ẹranko miran, gẹgẹ bi ẹkùn, ti o ni iyẹ-apa ẹiyẹ mẹrin li ẹhin rẹ̀; ẹranko na ni ori mẹrin pẹlu; a si fi agbara ijọba fun u.

7. Lẹhin eyi, mo ri ni iran oru, si kiyesi i, ẹranko kẹrin ti o burujù, ti o si lẹrù, ti o si lagbara gidigidi; o si ni ehin irin nla: o njẹ o si nfọ tũtu, o si fi ẹsẹ rẹ̀ tẹ̀ iyokù mọlẹ: o si yatọ si gbogbo awọn ẹranko ti o ṣiwaju rẹ̀; o si ni iwo mẹwa.

8. Mo si kiyesi awọn iwo na, si wò o, iwo kekere miran kan si jade larin wọn, niwaju eyiti a fa mẹta tu ninu awọn iwo iṣaju: si kiyesi i, oju gẹgẹ bi oju enia wà lara iwo yi, ati ẹnu ti nsọ ohun nlanlà.

9. Mo si wò titi a fi sọ̀ itẹ́ wọnni kalẹ titi Ẹni-àgba ọjọ na fi joko, aṣọ ẹniti o fún gẹgẹ bi ẹ̀gbọn owu, irun ori rẹ̀ si dabi irun agutan ti o mọ́: itẹ rẹ̀ jẹ ọwọ iná, ayika-kẹkẹ rẹ̀ si jẹ jijo iná.

10. Iṣàn iná nṣẹyọ, o si ntu jade lati iwaju rẹ̀ wá; awọn ẹgbẹ̃gbẹrun nṣe iranṣẹ fun u, ati awọn ẹgbẹgbarun nigba ẹgbarun duro niwaju rẹ̀: awọn onidajọ joko, a si ṣi iwe wọnni silẹ.

11. Nigbana ni mo wò nitori ohùn ọ̀rọ nla ti iwo na nsọ: mo si wò titi a fi pa ẹranko na, a si pa ara rẹ̀ run, a si sọ ọ sinu ọwọ iná ti njo.

12. Bi o ṣe ti awọn ẹranko iyokù ni, a ti gba agbara wọn kuro: nitori a ti yàn akokò ati ìgba fun wọn bi olukulùku yio ti pẹ tó.

13. Mo ri ni iran oru, si kiyesi i, ẹnikan bi Ọmọ enia wá pẹlu awọsanma ọrun, o si wá sọdọ Ẹni-Àgba ọjọ na, nwọn si mu u sunmọ iwaju rẹ̀.

14. A si fi agbara ijọba fun u, ati ogo, ati ijọba, ki gbogbo enia, ati orilẹ, ati ède, ki o le ma sìn i; agbara ijọba rẹ̀ si jẹ agbara ijọba ainipẹkun, eyiti a kì yio rekọja, ati ijọba rẹ̀, eyiti a kì yio le parun.

15. Ẹmi emi Danieli si rẹwẹsi ninu ara mi, iran ori mi si mu mi dãmu.

Ka pipe ipin Dan 7