Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dan 6:16-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Nigbana ni ọba paṣẹ, nwọn si mu Danieli wá, nwọn si gbé e sọ sinu iho kiniun. Ọba si dahùn o wi fun Danieli pe, Ọlọrun rẹ, ẹniti iwọ nsìn laisimi, on o gbà ọ la.

17. A si yi okuta kan wá, nwọn si gbé e ka oju iho na; ọba si fi oruka edidi rẹ̀ sami si i, ati oruka edidi awọn ijoye rẹ̀, ki ohunkohun máṣe yipada nitori Danieli.

18. Nigbana ni Ọba wọ̀ ãfin rẹ̀ lọ, o si fi oru na gbàwẹ: bẹ̃li a kò si gbé ohun-elo orin kan wá siwaju rẹ̀: orun kò si wá si oju rẹ̀.

19. Nigbana ni Ọba dide li afẹmọjumọ, o si yara kánkan lọ si ibi iho kiniun na.

20. Nigbati o si sunmọ iho na o fi ohùnrére ẹkun kigbe si Danieli: ọba dahùn o si wi fun Danieli pe, Danieli! iranṣẹ Ọlọrun alãye! Ọlọrun rẹ, ẹniti iwọ nsìn laisimi, ha le gbà ọ lọwọ awọn kiniun bi?

21. Nigbana ni Danieli wi fun ọba pe, ki ọba ki o pẹ.

22. Ọlọrun mi ti ran angeli rẹ̀, o si dì awọn kiniun na lẹnu, ti nwọn kò fi le pa mi lara: gẹgẹ bi a ti ri mi lailẹṣẹ niwaju rẹ̀; ati niwaju rẹ pẹlu, ọba, emi kò si ṣe ohun buburu kan.

Ka pipe ipin Dan 6