Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Titu 2:9-15 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Kí àwọn ẹrú fi ara wọn sí abẹ́ àṣẹ ọ̀gá wọn ninu ohun gbogbo. Kí wọn máa ṣe nǹkan tí yóo tẹ́ wọn lọ́rùn, kí wọn má máa fún wọn lésì.

10. Kí wọn má máa ja ọ̀gá wọn lólè. Ṣugbọn kí wọn jẹ́ olóòótọ́ ati ẹni tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ní ọ̀nà gbogbo. Báyìí ni wọn yóo fi ṣe ẹ̀kọ́ Ọlọrun Olùgbàlà wa lọ́ṣọ̀ọ́ ninu ohun gbogbo.

11. Nítorí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ti farahàn fún ìgbàlà gbogbo eniyan.

12. Ó ń tọ́ wa sọ́nà pé kí á kọ ìwà aibikita fún Ọlọrun ati ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ayé sílẹ̀, kí á máa farabalẹ̀. Kí á máa gbé ìgbé-ayé òdodo, kí á sì jẹ́ olùfọkànsìn ní ayé yìí.

13. Kí á máa dúró de ibukun tí à ń retí, ati ìfarahàn ògo Ọlọrun ẹni ńlá, ati ti Olùgbàlà wa Jesu Kristi,

14. ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún wa, láti rà wá pada kúrò ninu gbogbo agbára ẹ̀ṣẹ̀, ati láti wẹ̀ wá mọ́ láti fi wá ṣe ẹni tirẹ̀ tí yóo máa làkàkà láti ṣe iṣẹ́ rere.

15. Báyìí ni kí o máa wí fún wọn, kí o máa fi gbà wọ́n níyànjú kí o sì máa bá wọn wí nígbà gbogbo pẹlu àṣẹ. Má gbà fún ẹnikẹ́ni láti fojú tẹmbẹlu rẹ.

Ka pipe ipin Titu 2