Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Timoti Kinni 5:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Má máa fi ohùn líle bá àwọn àgbàlagbà wí, ṣugbọn máa gbà wọ́n níyànjú bíi baba rẹ. Máa ṣe sí àwọn ọdọmọkunrin bí ẹ̀gbọ́n ati àbúrò rẹ.

2. Mú àwọn àgbà obinrin bí ìyá; mú àwọn ọ̀dọ́ obinrin bí ẹ̀gbọ́n tabi àbúrò rẹ pẹlu ìwà mímọ́ ní ọ̀nà gbogbo.

3. Bu ọlá fún àwọn opó tí wọ́n jẹ́ alailẹnikan.

4. Ṣugbọn bí opó kan bá ní àwọn ọmọ tabi àwọn ọmọ-ọmọ, wọ́n gbọdọ̀ kọ́ láti ṣe ìtọ́jú ìdílé wọn, kí wọ́n san pada ninu ohun tí àwọn òbí wọn ti ṣe fún wọn. Èyí ni ohun tí ó dára lójú Ọlọrun.

5. Ṣugbọn ẹni tí ó bá jẹ́ opó nítòótọ́, tí kò ní ọmọ tabi ọmọ-ọmọ, Ọlọrun nìkan ni ó ń wò, tí ó ń bẹ̀, tí ó ń gbadura sí tọ̀sán-tòru.

6. Ṣugbọn opó tí ó bá ń gbádùn ara rẹ̀ káàkiri ti kú sáyé.

7. Àwọn ohun tí o óo máa pa láṣẹ nìyí, kí wọ́n lè jẹ́ aláìlẹ́gàn.

8. Bí ẹnìkan kò bá pèsè fún àwọn ẹbí rẹ̀, pataki jùlọ fún àwọn ìdílé rẹ̀, olúwarẹ̀ ti lòdì sí ẹ̀sìn igbagbọ wa, ó sì burú ju alaigbagbọ lọ.

9. Má kọ orúkọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀ bí opó àfi ẹni tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò bá dín ní ọgọta ọdún, tí ó sì jẹ́ aya ọkọ kan,

Ka pipe ipin Timoti Kinni 5