Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Timoti Kinni 2:2-8 BIBELI MIMỌ (BM)

2. fún àwọn ọba, ati fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ipò gíga, pé kí á máa ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kí á máa gbé ìgbé-ayé bí olùfọkànsìn ati bí ọmọlúwàbí.

3. Irú adura báyìí dára, ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọrun Olùgbàlà wa,

4. ẹni tí ó fẹ́ kí gbogbo eniyan rí ìgbàlà, tí ó sì fẹ́ kí wọn ní ìmọ̀ òtítọ́.

5. Nítorí Ọlọrun kan ni ó wà, alárinà kan ni ó sì wà láàrin Ọlọrun ati eniyan; olúwarẹ̀ ni Kristi Jesu, tí òun náà jẹ́ eniyan,

6. tí ó fi ara rẹ̀ ṣe ìràpadà fún gbogbo eniyan. Èyí ni ẹ̀rí pé, Ọlọrun ṣe ètò pé kí gbogbo eniyan lè ní ìgbàlà nígbà tí àkókò rẹ̀ tó.

7. Òtítọ́ ni mò ń sọ, n kò purọ́, pé ohun tí a yàn mí láti jẹ́ akéde ati aposteli sí ni pé kí n jẹ́ olùkọ́ni fún àwọn tí kì í ṣe Juu nípa nǹkan tí ó jẹ mọ́ igbagbọ ati òtítọ́ Ọlọrun.

8. Nítorí náà mo fẹ́ kí gbogbo eniyan máa gbadura ninu gbogbo ìsìn, kí wọn máa gbé ọwọ́ adura sókè pẹlu ọkàn kan, láìsí èrò ibinu tabi ọkàn àríyànjiyàn.

Ka pipe ipin Timoti Kinni 2