Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Timoti Kinni 1:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Èmi Paulu, òjíṣẹ́ Kristi Jesu nípa àṣẹ Ọlọrun Olùgbàlà wa, ati ti Kristi Jesu ìrètí wa, ni mò ń kọ ìwé yìí–

2. Sí Timoti ọmọ mi tòótọ́ ninu igbagbọ.Kí oore-ọ̀fẹ́, àánú ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba, ati Kristi Jesu Oluwa wa, kí ó máa wà pẹlu rẹ.

3. Nígbà tí mò ń lọ sí Masedonia, mo gbà ọ́ níyànjú pé kí o dúró ní Efesu, kí o pàṣẹ fún àwọn kan kí wọn má ṣe kọ́ eniyan ní ẹ̀kọ́ tí ń ṣini lọ́nà,

4. kí wọn má jókòó ti àwọn ìtàn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ati ìtàn ìrandíran tí kò lópin, tí ó máa ń mú àríyànjiyàn wá, dípò ẹ̀kọ́ nípa Ọlọrun tí a mọ̀ nípa igbagbọ.

5. Ìdí tí mo fi pa àṣẹ yìí ni láti ta ìfẹ́ àtọkànwá jí ninu rẹ, pẹlu ẹ̀rí ọkàn rere ati igbagbọ tí kò lẹ́tàn.

Ka pipe ipin Timoti Kinni 1