Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Romu 5:5-15 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ìrètí irú èyí kì í ṣe ohun tí yóo dójú tì wá, nítorí a ti tú ìfẹ́ Ọlọrun dà sí wa lọ́kàn nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó fún wa.

6. Nítorí nígbà tí a jẹ́ aláìlera, ní àkókò tí ó wọ̀, Kristi kú fún àwa tí kò ka Ọlọrun sí.

7. Bóyá ni a lè rí ẹni tí yóo fẹ́ kú fún olódodo. Ṣugbọn ó ṣeéṣe kí á rí ẹni tí yóo ní ìgboyà láti kú fún eniyan rere.

8. Ṣugbọn Ọlọrun fihàn wá pé òun fẹ́ràn wa ní ti pé nígbà tí a ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.

9. Bí ó bá lè kú fún wa nígbà tí a sì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, nisinsinyii tí Ọlọrun ti dá wa láre nítorí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, yóo fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, a óo sì torí rẹ̀ gbà wá kúrò ninu ibinu tí ń bọ̀.

10. Bí ikú Ọmọ Ọlọrun bá sọ àwa tí a jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun di ọ̀rẹ́ rẹ̀, nígbà yìí tí a wá di ọ̀rẹ́ Ọlọrun tán, ajinde ọmọ rẹ̀ yóo gbà wá là ju tàtẹ̀yìnwá lọ.

11. Kì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣugbọn à ń yọ̀ ninu Ọlọrun nítorí ohun tí ó ṣe nípa Oluwa wa Jesu Kristi, ẹni tí ó sọ wá di ọ̀rẹ́ Ọlọrun ní àkókò yìí.

12. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe ti ipasẹ̀ ẹnìkan wọ inú ayé, tí ikú sì ti ipasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọlé, bẹ́ẹ̀ náà ni ikú ṣe ran gbogbo eniyan, nítorí pé gbogbo eniyan ni ó ṣẹ̀.

13. Ẹ̀ṣẹ̀ ni ó ṣiwaju Òfin dáyé, bẹ́ẹ̀ bí kò bá sí òfin a kì í ka ẹ̀ṣẹ̀ sí eniyan lọ́rùn.

14. Ṣugbọn ikú ti jọba ní tirẹ̀ láti ìgbà Adamu títí dé ìgbà Mose, àwọn tí kò tilẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ nípa rírú òfin bíi Adamu, pẹlu àwọn tí ikú pa, Adamu tí ó jẹ́ àpẹẹrẹ irú ẹni tó ń bọ̀.

15. Kì í ṣe bí eniyan ṣe rú òfin tó ni Ọlọrun fi ń wọn ìfẹ́ ati àánú rẹ̀. Bí gbogbo eniyan bá jogún ikú nítorí aṣemáṣe ẹnìkan, oore-ọ̀fẹ́ ati àánú tí Ọlọrun fún gbogbo eniyan láti ọwọ́ ẹnìkan, àní Jesu Kristi, ó pọ̀ pupọ; ó pọ̀ ju ogún ikú lọ.

Ka pipe ipin Romu 5