Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Romu 5:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Níwọ̀n ìgbà tí a ti dá wa láre nítorí pé a gba Ọlọrun gbọ́, kò sí ìjà mọ́ láàrin àwa ati Ọlọrun: Jesu Kristi Oluwa wa ti parí ìjà.

2. Ọpẹ́lọpẹ́ rẹ̀ ni a fi rí ọ̀nà gbà dé ipò oore-ọ̀fẹ́ tí a wà ninu rẹ̀ yìí. A wá ń yọ̀ ninu ògo Ọlọrun tí à ń retí.

3. Èyí nìkan kọ́. A tún ń fi àwọn ìṣòro wa ṣe ọlá, nítorí a mọ̀ pé àyọrísí ìṣòro ni ìfaradà;

4. àyọrísí ìfaradà ni ìyege ìdánwò; àyọrísí ìyege ìdánwò ni ìrètí.

5. Ìrètí irú èyí kì í ṣe ohun tí yóo dójú tì wá, nítorí a ti tú ìfẹ́ Ọlọrun dà sí wa lọ́kàn nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó fún wa.

6. Nítorí nígbà tí a jẹ́ aláìlera, ní àkókò tí ó wọ̀, Kristi kú fún àwa tí kò ka Ọlọrun sí.

7. Bóyá ni a lè rí ẹni tí yóo fẹ́ kú fún olódodo. Ṣugbọn ó ṣeéṣe kí á rí ẹni tí yóo ní ìgboyà láti kú fún eniyan rere.

8. Ṣugbọn Ọlọrun fihàn wá pé òun fẹ́ràn wa ní ti pé nígbà tí a ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.

9. Bí ó bá lè kú fún wa nígbà tí a sì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, nisinsinyii tí Ọlọrun ti dá wa láre nítorí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, yóo fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, a óo sì torí rẹ̀ gbà wá kúrò ninu ibinu tí ń bọ̀.

10. Bí ikú Ọmọ Ọlọrun bá sọ àwa tí a jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun di ọ̀rẹ́ rẹ̀, nígbà yìí tí a wá di ọ̀rẹ́ Ọlọrun tán, ajinde ọmọ rẹ̀ yóo gbà wá là ju tàtẹ̀yìnwá lọ.

Ka pipe ipin Romu 5