Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Romu 15:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ó yẹ kí àwa tí a jẹ́ alágbára ninu igbagbọ máa fara da àwọn nǹkan tí àwọn tí igbagbọ wọn kò tíì fẹsẹ̀ múlẹ̀ bá ń ṣiyèméjì lé lórí. A kò gbọdọ̀ máa tẹ́ ara wa nìkan lọ́rùn.

2. Olukuluku wa níláti máa ṣe ohun tí yóo tẹ́ ẹnìkejì rẹ̀ lọ́rùn fún ire rẹ̀ ati fún ìdàgbàsókè rẹ̀.

3. Nítorí Kristi kò ṣe nǹkan tí ó tẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn. Dípò bẹ́ẹ̀ ó ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀, “Èmi ni ẹ̀gàn àwọn ẹni tí ó ń gàn ọ́ rẹ́ lára.”

4. Nítorí fún àtikọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ ni a ṣe kọ ohunkohun tí a ti kọ tẹ́lẹ̀, ìdí rẹ̀ ni pé kí ìgboyà ati ìwúrí tí Ìwé Mímọ́ ń fún wa lè fún wa ní ìrètí.

5. Kí Ọlọrun, tí ó ń fún wa ní ìrọ́jú ati ìwúrí, jẹ́ kí ẹ ní ọkàn kan náà sí ara yín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Kristi Jesu,

6. kí ẹ fi inú kan ati ohùn kan yin Ọlọrun ati Baba Oluwa Jesu Kristi.

7. Nítorí náà, ẹ fa ara yín mọ́ra gẹ́gẹ́ bí Kristi ti gbà yín, kí á lè fi ògo fún Ọlọrun.

8. Ohun tí mò ń sọ ni pé Kristi ti di iranṣẹ fún àwọn tí ó kọlà, láti mú òtítọ́ Ọlọrun ṣẹ, kí ó lè mú àwọn ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún àwọn baba-ńlá ṣẹ,

9. ati láti jẹ́ kí àwọn tí kò kọlà lè yin Ọlọrun nítorí àánú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní àkọsílẹ̀ pé,“Nítorí èyí, n óo yìn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,n óo kọrin sí orúkọ rẹ.”

10. Ó tún sọ pé,“Ẹ bá àwọn eniyan rẹ̀ yọ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè.”

Ka pipe ipin Romu 15