Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Romu 11:5-16 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Bẹ́ẹ̀ náà ló rí ní àkókò yìí, àwọn kan kù tí Ọlọrun yàn nítorí oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀.

6. Tí ó bá wá jẹ́ pé nítorí oore-ọ̀fẹ́ ni Ọlọrun fi yàn wọ́n, kò tún lè jẹ́ nítorí iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, oore-ọ̀fẹ́ kò ní jẹ́ oore-ọ̀fẹ́ mọ́.

7. Kí wá ni? Ohun tí Israẹli ń wá kò tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́. Ṣugbọn ó tẹ àwọn díẹ̀ tí a yàn ninu wọn lọ́wọ́. Etí àwọn yòókù di sí ìpè Ọlọrun,

8. gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé,“Ọlọrun fún wọn ní iyè tí ó ra,ojú tí kò ríran,ati etí tí kò gbọ́ràn títí di òní olónìí.”

9. Dafidi náà sọ pé,“Jẹ́ kí àsè wọn di tàkúté ati àwọ̀n,kí ó gbé wọn ṣubú,kí ó mú ẹ̀san bá wọn.

10. Jẹ́ kí ojú wọn ṣókùnkùn,kí wọn má lè ríran.Jẹ́ kí ẹ̀yìn wọn tẹ̀,kí wọn má lè nàró mọ́.”

11. Mo tún bèèrè: ǹjẹ́ nígbà tí àwọn Juu kọsẹ̀, ṣé wọ́n ṣubú gbé ni? Rárá o! Ṣugbọn nítorí ìṣìnà wọn ni ìgbàlà fi dé ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, kí àwọn Juu baà lè máa jowú.

12. Ǹjẹ́ bí ìṣìnà wọn bá ṣe ayé ní anfaani, bí ìkùnà wọn bá ṣe orílẹ̀-èdè yòókù ní anfaani, báwo ni anfaani náà yóo ti pọ̀ tó nígbà tí gbogbo wọn bá ṣe ojúṣe wọn?

13. Ẹ̀yin ará, tí ẹ kì í ṣe Juu ni mò ń bá sọ̀rọ̀ nisinsinyii. Níwọ̀n ìgbà tí mo jẹ́ Aposteli láàrin yín, mò ń ṣe àpọ́nlé iṣẹ́ mi,

14. pé bóyá mo lè ti ipa bẹ́ẹ̀ mú àwọn eniyan mi jowú yín, kí n lè gba díẹ̀ ninu wọn là.

15. Nítorí bí kíkọ̀ tí Ọlọrun kọ̀ wọ́n sílẹ̀ bá mú kí aráyé bá Ọlọrun rẹ́, kí ni yóo ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ọlọrun bá gbà wọ́n mọ́ra? Ǹjẹ́ òkú pàápàá kò ní jí dìde?

16. Bí a bá ya ìyẹ̀fun tí a kọ́kọ́ rí ninu ìkórè sí mímọ́, a ti ya burẹdi tí a fi ṣe sí mímọ́. Bí a bá ya gbòǹgbò igi sí mímọ́, a ti ya àwọn ẹ̀ka igi náà sí mímọ́.

Ka pipe ipin Romu 11