Mo tún bèèrè: ǹjẹ́ nígbà tí àwọn Juu kọsẹ̀, ṣé wọ́n ṣubú gbé ni? Rárá o! Ṣugbọn nítorí ìṣìnà wọn ni ìgbàlà fi dé ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, kí àwọn Juu baà lè máa jowú.