Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Peteru Kinni 4:3-13 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ní ìgbà kan rí ẹ ní anfaani tó láti ṣe àwọn ohun tí àwọn abọ̀rìṣà ń ṣe. Ẹ̀ ń hùwà wọ̀bìà, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ìmutípara, ayé ìjẹkújẹ, ìmukúmu ati ìbọ̀rìṣà tí ó jẹ́ èèwọ̀.

4. Nisinsinyii ó jẹ́ ohun ìjọjú fún àwọn ẹlẹgbẹ́ yín àtijọ́, nígbà tí ẹ kò bá wọn lọ́wọ́ sí ayé ìjẹkújẹ mọ́, wọn óo wá máa fi yín ṣe ẹlẹ́yà.

5. Ṣugbọn wọn óo dáhùn fún ìwà wọn níwájú ẹni tí ó ṣetán láti ṣe ìdájọ́ alààyè ati òkú.

6. Nítorí rẹ̀ ni a ṣe waasu ìyìn rere fún àwọn òkú, pé bí wọ́n bá tilẹ̀ gba ìdájọ́ bí gbogbo eniyan ti níláti gbà ninu ara, sibẹ wọn óo wà láàyè ninu ẹ̀mí nípa ti Ọlọrun.

7. Òpin ohun gbogbo súnmọ́ tòsí. Nítorí náà ẹ fi òye ati ìwà pẹ̀lẹ́ gbé ìgbé-ayé yín ninu adura.

8. Ju ohun gbogbo lọ, ẹ ní ìfẹ́ tí ó jinlẹ̀ sí ara yín, nítorí ìfẹ́ bo ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.

9. Ẹ lawọ́ sí ara yín láìní ìkùnsínú.

10. Olukuluku yín ní ẹ̀bùn tirẹ̀. Ẹ máa lo ẹ̀bùn yín fún ire ọmọnikeji yín, gẹ́gẹ́ bí ìríjú oríṣìíríṣìí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun.

11. Bí ẹnikẹ́ni bá ń sọ̀rọ̀, kí ó mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Ọlọrun ni òun ń sọ. Bí ẹnikẹ́ni bá ṣe iṣẹ́ iranṣẹ, kí ó ṣe é pẹlu gbogbo agbára tí Ọlọrun fún un. Ninu ohun gbogbo ẹ máa hùwà kí ògo lè jẹ́ ti Ọlọrun nípasẹ̀ Jesu Kristi: òun ni ògo ati agbára jẹ́ tirẹ̀ lae ati laelae. Amin.

12. Ẹ̀yin olùfẹ́ mi, ẹ má jẹ́ kí ó jọ yín lójú bí wọ́n bá wa iná jó yín láti dán yín wò, bí ẹni pé ohun tí ojú kò rí rí ni ó dé.

13. Èyí sọ yín di alábàápín ninu ìjìyà Kristi. Ẹ máa yọ̀. Nígbà tí ó bá pada dé ninu ògo rẹ̀, ayọ̀ ńlá ni ẹ óo yọ̀.

Ka pipe ipin Peteru Kinni 4