Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Peteru Kinni 4:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí Kristi ti jìyà ninu ara, kí ẹ̀yin náà di ọkàn yín ní àmùrè láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí ẹni tí ó bá jìyà nípa ti ara ti bọ́ lọ́wọ́ agbára ẹ̀ṣẹ̀.

2. Má tún máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀dá mọ́, ṣugbọn máa ṣe ìfẹ́ Ọlọrun ninu gbogbo ìgbé-ayé rẹ tí ó kù.

3. Ní ìgbà kan rí ẹ ní anfaani tó láti ṣe àwọn ohun tí àwọn abọ̀rìṣà ń ṣe. Ẹ̀ ń hùwà wọ̀bìà, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ìmutípara, ayé ìjẹkújẹ, ìmukúmu ati ìbọ̀rìṣà tí ó jẹ́ èèwọ̀.

4. Nisinsinyii ó jẹ́ ohun ìjọjú fún àwọn ẹlẹgbẹ́ yín àtijọ́, nígbà tí ẹ kò bá wọn lọ́wọ́ sí ayé ìjẹkújẹ mọ́, wọn óo wá máa fi yín ṣe ẹlẹ́yà.

5. Ṣugbọn wọn óo dáhùn fún ìwà wọn níwájú ẹni tí ó ṣetán láti ṣe ìdájọ́ alààyè ati òkú.

6. Nítorí rẹ̀ ni a ṣe waasu ìyìn rere fún àwọn òkú, pé bí wọ́n bá tilẹ̀ gba ìdájọ́ bí gbogbo eniyan ti níláti gbà ninu ara, sibẹ wọn óo wà láàyè ninu ẹ̀mí nípa ti Ọlọrun.

7. Òpin ohun gbogbo súnmọ́ tòsí. Nítorí náà ẹ fi òye ati ìwà pẹ̀lẹ́ gbé ìgbé-ayé yín ninu adura.

8. Ju ohun gbogbo lọ, ẹ ní ìfẹ́ tí ó jinlẹ̀ sí ara yín, nítorí ìfẹ́ bo ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.

9. Ẹ lawọ́ sí ara yín láìní ìkùnsínú.

Ka pipe ipin Peteru Kinni 4