Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Peteru Kinni 2:4-19 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ẹ wá sọ́dọ̀ ẹni tíí ṣe òkúta ààyè tí eniyan kọ̀ sílẹ̀ ṣugbọn tí Ọlọrun yàn, tí ó ṣe iyebíye lójú rẹ̀.

5. Ẹ fi ara yín kọ́ ilé ẹ̀mí bí òkúta ààyè, níbi tí ẹ óo jẹ́ alufaa mímọ́, tí ẹ óo máa rú ẹbọ ẹ̀mí tí Ọlọrun yóo tẹ́wọ́ gbà nípasẹ̀ Jesu Kristi.

6. Nítorí ó wà ninu Ìwé Mímọ́ pé,“Mo fi òkúta lélẹ̀ ní Sioni,àṣàyàn òkúta igun ilé tí ó ṣe iyebíye.Ojú kò ní ti ẹni tí ó bá gbà á gbọ́.”

7. Nítorí náà, ọlá ni fún ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́. Ṣugbọn fún àwọn tí kò gbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí,“Òkúta tí àwọn mọlémọlé kọ̀ sílẹ̀,òun ni ó di pataki igun ilé.”

8. Ati,“Òkúta tí yóo mú eniyan kọsẹ̀,ati àpáta tí yóo gbé eniyan ṣubú.”Àwọn tí ó ṣubú ni àwọn tí kò gba ọ̀rọ̀ náà gbọ́. Bẹ́ẹ̀, bí ti irú wọn ti níláti rí nìyí.

9. Ṣugbọn ẹ̀yin ni orílẹ̀-èdè tí Ọlọrun yàn, alufaa ọlọ́lá, ẹ̀yà mímọ́, eniyan tí Ọlọrun ṣe ní tirẹ̀, kí ẹ lè sọ àwọn iṣẹ́ ńlá tí ẹni tí ó pè yín láti inú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tí ó yani lẹ́nu.

10. Ẹ̀yin tí ẹ kì í ṣe eniyan nígbà kan, ṣugbọn nisinsinyii ẹ di eniyan Ọlọrun. Ẹ̀yin tí ẹ kò tíì rí àánú gbà tẹ́lẹ̀ ṣugbọn nisinsinyii ẹ di ẹni tí Ọlọrun ṣàánú fún.

11. Ẹ̀yin olùfẹ́ tí ẹ jẹ́ àlejò ní ilẹ̀ àjèjì, mo bẹ̀ yín, ẹ jìnnà sí àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara tí ó ń bá ọkàn jagun.

12. Kí ìgbé-ayé yín láàrin àwọn abọ̀rìṣà jẹ́ èyí tí ó dára, tí ó fi jẹ́ pé bí wọ́n bá tilẹ̀ ń sọ̀rọ̀ yín ní àìdára, sibẹ nígbà tí wọ́n bá ṣe akiyesi ìwà rere yín, wọn yóo yin Ọlọrun lógo ní ọjọ́ ìdájọ́.

13. Ẹ fi ara yín sábẹ́ òfin ìjọba ilẹ̀ yín nítorí ti Oluwa, ìbáà ṣe ọba gẹ́gẹ́ bí olórí,

14. tabi aṣojú ọba gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó rán láti jẹ àwọn tí ó bá ń ṣe burúkú níyà, ati láti yin àwọn tí ó bá ń ṣe rere.

15. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ Ọlọrun pé nípa ìwà rere yín, kí kẹ́kẹ́ pamọ́ àwọn aṣiwèrè ati àwọn òpè lẹ́nu.

16. Ẹ máa hùwà bí ẹni tí ó ní òmìnira, ṣugbọn kì í ṣe òmìnira láti bo ìwà burúkú mọ́lẹ̀. Ẹ máa hùwà bí iranṣẹ Ọlọrun.

17. Ẹ máa yẹ́ gbogbo eniyan sí. Ẹ máa fẹ́ràn àwọn onigbagbọ. Ẹ bẹ̀rù Ọlọrun. Ẹ máa bu ọlá fún ọba.

18. Ẹ̀yin ọmọ-ọ̀dọ̀, ẹ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ọ̀gá yín ninu gbogbo nǹkan pẹlu ìbẹ̀rù, kì í ṣe fún àwọn ọ̀gá tí ó ní inú rere, tí wọ́n sì ń ṣe ẹ̀tọ́ si yín nìkan, ṣugbọn fún àwọn tí wọ́n rorò pẹlu.

19. Nítorí ó dára kí eniyan farada ìyà tí kò tọ́ sí i tí ó bá ronú ti Ọlọrun.

Ka pipe ipin Peteru Kinni 2