Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Peteru Keji 3:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, èyí ni ìwé keji tí mo kọ si yín. Ninu ìwé mejeeji, mò ń ji yín pẹ́pẹ́, láti ran yín létí àwọn ohun tí ẹ mọ̀, kí ẹ lè fi ọkàn tòótọ́ rò wọ́n jinlẹ̀.

2. Ẹ ranti àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii ti sọ ati òfin Oluwa wa ati Olùgbàlà tí ẹ gbà lọ́wọ́ aposteli yín.

3. Ní àkọ́kọ́, kí ẹ mọ èyí pé ní ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn tí wọn óo máa fi ẹ̀sìn ṣe ẹlẹ́yà yóo wá, tí wọn óo máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn.

4. Wọn óo máa sọ pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí ìlérí pé Jesu tún ń pada bọ̀? Nítorí láti ìgbà tí àwọn baba wa ninu igbagbọ ti lọ tán, bákan náà ni gbogbo nǹkan rí láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé!”

5. Nítorí wọ́n fi ojú fo èyí dá pé, láti ìgbà àtijọ́ ni àwọn ọ̀run ti wà, ati pé láti inú omi ni ilẹ̀ ti jáde nípa àṣẹ Ọlọrun.

6. Omi kan náà ni Ọlọrun fi pa ayé tí ó ti wà rí run.

7. Ṣugbọn àṣẹ kan náà ni Ọlọrun fi pa àwọn ọ̀run ati ayé ti àkókò yìí mọ́ kí ó lè dáná sun ún, ó ń fi wọ́n pamọ́ títí di ọjọ́ ìdájọ́ nígbà tí a óo pa àwọn eniyan tí kò bẹ̀rù Ọlọrun run.

8. Ẹ̀yin ará, ẹ má fi ojú fo èyí dá, pé níwájú Oluwa ọjọ́ kan dàbí ẹgbẹrun ọdún, ẹgbẹrun ọdún sì dàbí ọjọ́ kan.

9. Oluwa kò jáfara nípa ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti rò, ṣugbọn ó ń mú sùúrù fun yín ni. Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé ṣugbọn ó fi ààyè sílẹ̀ kí gbogbo eniyan lè ronupiwada.

10. Ṣugbọn bí olè ni ọjọ́ Oluwa yóo dé. Ní ọjọ́ náà, àwọn ọ̀run yóo parẹ́ pẹlu ariwo ńlá bí ìgbà tí iná ńlá bá ń jó ìgbẹ́. Àwọn ẹ̀dá ojú ọ̀run yóo fò, wọ́n óo sì jóná. Ayé ati gbogbo nǹkan inú rẹ̀ yóo wá wà ní ìhòòhò.

11. Nígbà tí ìparun ń bọ̀ wá bá gbogbo nǹkan báyìí, irú ìgbé-ayé wo ni ó yẹ kí ẹ máa gbé? Ẹ níláti jẹ́ eniyan ọ̀tọ̀ ati olùfọkànsìn,

12. kí ẹ máa retí ọjọ́ Ọlọrun, kí ẹ máa ṣe akitiyan pé kí ó tètè dé. Ní ọjọ́ náà, àwọn ọ̀run yóo parun, gbogbo ẹ̀dá ojú ọ̀run yóo yọ́ ninu iná.

Ka pipe ipin Peteru Keji 3