Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 9:16-29 BIBELI MIMỌ (BM)

16. “Kò sí ẹni tíí fi ìrépé aṣọ titun tí kò ì tíì wọ omi rí lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù, Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìrépé aṣọ titun náà yóo súnkì lára ògbólógbòó ẹ̀wù náà, yíya rẹ̀ yóo wá burú ju ti àkọ́kọ́ lọ.

17. Kò sí ẹni tíí fi ọtí titun sinu ògbólógbòó àpò awọ. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ògbólógbòó àpò awọ náà yóo bẹ́; ati ọtí ati àpò yóo sì ṣòfò. Ṣugbọn ninu àpò awọ titun ni à ń fi ọtí titun sí, ati ọtí ati àpò yóo wà ní ìpamọ́.”

18. Bí Jesu tí ń sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn, ìjòyè kan wá, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Ọmọdebinrin mi ṣẹ̀ṣẹ̀ kú nisinsinyii ni, ṣugbọn wá gbé ọwọ́ rẹ lé e, yóo sì yè.”

19. Jesu bá dìde. Ó ń tẹ̀lé e lọ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

20. Obinrin kan wà, tí nǹkan oṣù rẹ̀ kò tètè dá rí fún ọdún mejila, ó gba ẹ̀yìn wá, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ Jesu;

21. nítorí ó ń sọ ninu ọkàn rẹ̀ pé, “Bí mo bá sá ti lè fi ọwọ́ kan etí aṣọ rẹ̀, ara mi yóo dá.”

22. Jesu bá yipada, ó rí obinrin náà, ó ní, “Ṣe ara gírí, ọmọbinrin. Igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá.” Ara obinrin náà bá dá láti àkókò náà lọ.

23. Nígbà tí Jesu dé ilé ìjòyè náà, ó rí àwọn tí wọn ń fun fèrè ati ọ̀pọ̀ eniyan tí wọn ń ké.

24. Ó ní, “Ẹ sún sẹ́yìn, nítorí ọmọde náà kò kú, ó ń sùn ni.” Wọ́n bá ń fi í ṣe ẹlẹ́yà.

25. Lẹ́yìn tí ó ti lé àwọn eniyan jáde, ó wọ inú ilé, ó mú ọmọbinrin náà lọ́wọ́, ọmọbinrin náà bá dìde.

26. Òkìkí rẹ̀ kàn ká gbogbo agbègbè náà.

27. Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀, àwọn afọ́jú meji kan tẹ̀lé e, wọ́n ń kígbe pé, “Ọmọ Dafidi, ṣàánú wa.”

28. Nígbà tí ó wọ inú ilé, àwọn afọ́jú náà tọ̀ ọ́ lọ. Jesu bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ gbàgbọ́ pé mo lè wò yín sàn?”Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa.”

29. Ó bá fi ọwọ́ kàn wọ́n lójú, ó ní, “Kí ó rí fun yín gẹ́gẹ́ bí igbagbọ yín.”

Ka pipe ipin Matiu 9