Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 8:18-27 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Nígbà tí Jesu rí ọ̀pọ̀ eniyan tí wọ́n yí i ká, ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọn kọjá sí òdìkejì òkun.

19. Amòfin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, mo fẹ́ máa tẹ̀lé ọ níbikíbi tí o bá ń lọ.”

20. Jesu wí fún un pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́; ṣugbọn Ọmọ-Eniyan kò ní ibi tí yóo gbé orí rẹ̀ lé.”

21. Ẹlòmíràn ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Alàgbà, jẹ́ kí n kọ́ lọ sìnkú baba mi.”

22. Ṣugbọn Jesu sọ fún un pé, “Ìwọ tẹ̀lé mi, jẹ́ kí àwọn òkú máa sin òkú ara wọn.”

23. Jesu wọ ọkọ̀ ojú omi kan, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tẹ̀lé e.

24. Ìgbì líle kan sì dé lójú omi òkun; ó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé omi fẹ́rẹ̀ bo ọkọ̀; ṣugbọn Jesu sùnlọ.

25. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá lọ jí i; wọ́n ní, “Oluwa, gbà wá là, à ń ṣègbé lọ!”

26. Ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ ti ṣe lójo bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin onigbagbọ kékeré wọnyi?” Ó bá dìde, ó bá afẹ́fẹ́ ati òkun wí, ìdákẹ́rọ́rọ́ ńlá bá dé.

27. Ẹnu ya àwọn eniyan náà. Wọ́n ní, “Irú eniyan wo ni èyí, tí afẹ́fẹ́ ati òkun ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu?”

Ka pipe ipin Matiu 8