Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 26:50-63 BIBELI MIMỌ (BM)

50. Jesu sọ fún un pé, “Ọ̀rẹ́ kí ló dé o?”Nígbà náà ni àwọn eniyan wá, wọ́n ṣùrù mọ́ Jesu, wọ́n mú un.

51. Ọ̀kan ninu àwọn tí ó wà pẹlu Jesu bá na ọwọ́, ó fa idà yọ, ó sì fi ṣá ẹrú Olórí Alufaa kan, ó gé e létí.

52. Ṣugbọn Jesu sọ fún un pé, “Ti idà rẹ bọ inú akọ rẹ̀ pada, nítorí gbogbo àwọn tí ó bá ń fa idà yọ, idà ni a óo fi pa wọ́n.

53. Tabi o kò mọ̀ pé mo lè ké pe Baba mi, kí ó fún mi ní ẹgbaagbeje angẹli nisinsinyii?

54. Ṣugbọn bí mo bá ṣe bẹ́ẹ̀ báwo ni Ìwé Mímọ́ yóo ti ṣe ṣẹ pé bẹ́ẹ̀ ni ó gbọdọ̀ rí?”

55. Jesu bá sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ jáde wá mú mi pẹlu idà ati kùmọ̀ bí ìgbà tí ẹ wá mú olè. Ojoojumọ ni mò ń jókòó ninu Tẹmpili láti kọ́ àwọn eniyan. Ẹ kò mú mi nígbà náà!

56. Ṣugbọn gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ àwọn wolii lè ṣẹ ni.”Gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bá fi í sílẹ̀, wọ́n sálọ.

57. Àwọn tí wọ́n mú Jesu fà á lọ sọ́dọ̀ Kayafa Olórí Alufaa, níbi tí àwọn amòfin ati àwọn àgbà ti pé jọ sí.

58. Peteru ń tẹ̀lé Jesu, ó ń bọ̀ lẹ́yìn patapata, títí ó fi dé àgbàlá Olórí Alufaa. Ó wọlé, ó jókòó pẹlu àwọn ẹ̀ṣọ́ láti rí ibi tí gbogbo rẹ̀ yóo yọrí sí.

59. Àwọn olórí alufaa ati gbogbo ìgbìmọ̀ ń wá ẹ̀rí èké tí ó lè kóbá Jesu kí wọn baà lè pa á.

60. Ṣugbọn wọn kò rí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọpọlọpọ ni àwọn ẹlẹ́rìí-èké tí wọ́n yọjú. Ní ìgbẹ̀yìn àwọn meji kan wá.

61. Wọ́n ní, “Ọkunrin yìí sọ pé, ‘Mo lè wó Tẹmpili Ọlọrun yìí, kí n sì tún un kọ́ ní ọjọ́ mẹta.’ ”

62. Olórí Alufaa bá dìde, ó ní, “O kò fèsì rárá? Àbí o kò gbọ́ ohun tí wọ́n sọ pé o wí?”

63. Ṣugbọn Jesu kò fọhùn. Olórí Alufaa wá sọ fún un pé, “Mo fi Ọlọrun alààyè bẹ̀ ọ́, sọ fún wa bí ìwọ ni Mesaya, Ọmọ Ọlọrun.”

Ka pipe ipin Matiu 26