Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 26:22-35 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Ọkàn wọn dàrú pupọ; ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ń bèèrè pé, “Kò sá lè jẹ́ èmi ni, Oluwa?”

23. Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹni tí ó ń fi òkèlè run ọbẹ̀ ninu àwo kan náà pẹlu mi ni ẹni náà tí yóo fi mí fún àwọn ọ̀tá.

24. Ọmọ-Eniyan ń lọ gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ gbé! Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i.”

25. Nígbà náà ni Judasi, ẹni tí ó fi í fún àwọn ọ̀tá, bi í pé, “Àbí èmi ni, Olùkọ́ni?”Jesu dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ sọ ọ́.”

26. Nígbà tí wọn ń jẹun, Jesu mú burẹdi, ó gbadura sí i, ó bù ú, ó bá fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀; ó ní, “Ẹ gbà, ẹ jẹ ẹ́, èyí ni ara mi.”

27. Nígbà tí ó mú ife, ó dúpẹ́, ó fi fún wọn, ó ní “Gbogbo yín ẹ mu ninu rẹ̀.

28. Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí a fi dá majẹmu, ẹ̀jẹ̀ tí a ta sílẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ọpọlọpọ eniyan.

29. Mo sọ fun yín, n kò ní mu ọtí èso àjàrà mọ́ títí di ọjọ́ náà tí n óo mu ún pẹlu yín ní ọ̀tun ní ìjọba Baba mi.”

30. Lẹ́yìn náà, wọ́n kọ orin kan, wọ́n bá jáde lọ sórí Òkè Olifi.

31. Nígbà náà Jesu sọ fún wọn pé, “Gbogbo yín ni ẹ óo pada lẹ́yìn mi ní alẹ́ yìí, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé,‘Ọwọ́ yóo tẹ olùṣọ́-aguntan,gbogbo agbo aguntan ni a óo fọ́nká!’

32. “Ṣugbọn lẹ́yìn tí a bá ti jí mi dìde, n óo ṣiwaju yín lọ sí Galili.”

33. Peteru dá a lóhùn pé, “Bí gbogbo àwọn yòókù bá tilẹ̀ pada lẹ́yìn rẹ, bíi tèmi kọ́!”

34. Jesu wí fún un pé, “Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé ní alẹ́ yìí, kí àkùkọ tó kọ, ìwọ yóo sẹ́ mi ní ẹẹmẹta.”

35. Peteru sọ fún un pé, “Bí mo bá tilẹ̀ níláti bá ọ kú, n kò ní sẹ́ ọ.”Bákan náà ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yòókù sọ.

Ka pipe ipin Matiu 26