Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 25:32-46 BIBELI MIMỌ (BM)

32. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo péjọ níwájú rẹ̀, yóo wá yà wọ́n sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, bí olùṣọ́-aguntan tíí ya àwọn aguntan sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ewúrẹ́.

33. Yóo fi àwọn olódodo sí ọwọ́ ọ̀tún, yóo fi àwọn ìyókù sí ọwọ́ òsì.

34. Nígbà náà ni ọba yóo sọ fún àwọn ti ọwọ́ ọ̀tún pé, ‘Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bukun. Ẹ wá jogún ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fun yín kí á tó dá ayé.

35. Nítorí nígbà tí ebi ń pa mí, ẹ fún mi ní oúnjẹ. Nígbà tí òùngbẹ ń gbẹ mí, ẹ fún mi ní omi mu. Nígbà tí mo jẹ́ àlejò, ẹ gbà mí sílé.

36. Nígbà tí mo wà níhòòhò, ẹ daṣọ bò mí. Nígbà tí mo ṣàìsàn, ẹ wá wò mí. Nígbà tí mo wà lẹ́wọ̀n, ẹ wá sọ́dọ̀ mi.’

37. “Nígbà náà ni àwọn olódodo yóo dáhùn pé, ‘Oluwa, nígbà wo ni a rí ọ tí ebi ń pa ọ́, tí a fún ọ ní oúnjẹ, tabi tí òùngbẹ ń gbẹ ọ́ tí a fún ọ ní omi mu?

38. Nígbà wo ni a rí ọ níhòòhò tí a daṣọ bò ọ́?

39. Nígbà wo ni a rí ọ tí o ṣàìsàn, tabi tí o wà lẹ́wọ̀n, tí a wá sọ́dọ̀ rẹ?’

40. Ọba yóo wá dá wọn lóhùn pé, ‘Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti ṣe é fún ọ̀kan ninu àwọn arakunrin mi tí ó kéré jùlọ, èmi ni ẹ ṣe é fún.’

41. “Nígbà náà ni yóo wá sọ fún àwọn tí ó wà ní ọwọ́ òsì pé, ‘Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin ẹni ègún. Ẹ lọ sinu iná àjóòkú tí a ti pèsè sílẹ̀ fún èṣù ati àwọn angẹli rẹ̀.

42. Nítorí nígbà tí ebi ń pa mí, ẹ kò fún mi ní oúnjẹ jẹ. Òùngbẹ ń gbẹ mí, ẹ kò fún mi ní omi mu.

43. Mo jẹ́ àlejò, ẹ kò gbà mí sílé. Mo wà ní ìhòòhò, ẹ kò daṣọ bò mí. Mo ṣàìsàn, mo wà lẹ́wọ̀n, ẹ kò wá wò mí.’

44. “Nígbà náà ni àwọn náà yóo bi í pé, ‘Oluwa, nígbà wo ni a rí ọ tí ebi ń pa ọ́, tabi tí òùngbẹ ń gbẹ ọ́, tabi tí o jẹ́ àlejò, tabi tí o wà ní ìhòòhò, tabi tí o ṣàìsàn, tabi tí o wà lẹ́wọ̀n, tí a kò bojútó ọ?’

45. Yóo wá dá wọn lóhùn pé, ‘Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, níwọ̀n ìgbà tí ẹ kò ti ṣe é fún ọ̀kan ninu àwọn tí ó kéré jùlọ wọnyi, èmi ni ẹ kò ṣe é fún.’

46. Àwọn wọnyi ni yóo lọ sinu ìyà àìlópin. Ṣugbọn àwọn olódodo yóo wọ ìyè ainipẹkun.”

Ka pipe ipin Matiu 25