Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 23:6-24 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Wọ́n fẹ́ràn ìjókòó ọlá níbi àsè. Wọ́n fẹ́ràn àga iwájú ní ilé ìpàdé.

7. Wọ́n fẹ́ràn kí eniyan máa kí wọn láàrin ọjà ati kí àwọn eniyan máa pè wọ́n ní ‘Olùkọ́ni.’

8. Ṣugbọn ẹ̀yin ní tiyín, ẹ má jẹ́ kí wọ́n pè yín ní ‘Olùkọ́ni,’ nítorí ẹnìkan ṣoṣo ni olùkọ́ni yín; arakunrin ni gbogbo yín jẹ́.

9. Ẹ má pe ẹnìkan ní ‘Baba’ ní ayé, nítorí ẹnìkan ṣoṣo ni Baba yín, ẹni tí ó wà ní ọ̀run.

10. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni pè yín ní ‘Ọ̀gá,’ nítorí ọ̀gá kanṣoṣo ni ẹ ní, òun ni Mesaya.

11. Ẹni tí ó bá lọ́lá jùlọ láàrin yín ni kí ó ṣe iranṣẹ yín.

12. Ẹni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a óo rẹ̀ sílẹ̀; ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óo gbé ga.

13. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin alárèékérekè wọnyi. Nítorí ẹ ti ìlẹ̀kùn ìjọba ọ̀run mọ́ àwọn eniyan, ẹ̀yin fúnra yín kò wọlé, bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí wọ́n fẹ́ wọlé, ẹ kò jẹ́ kí wọ́n wọlé.[

14. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati Farisi, alaiṣootọ; nítorí ẹ̀ ń jẹ ilé àwọn opó run; ẹ̀ ń fi adura gígùn ṣe ìbòjú. Nítorí èyí, ẹ óo gba ìdálẹ́bi pupọ.”]

15. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn, nítorí ẹ̀ ń la òkun ati oríṣìíríṣìí ìlú kọjá láti mú ẹyọ ẹnìkan láti orílẹ̀-èdè mìíràn wọ ẹ̀sìn yín. Nígbà tí ó bá ti wọ ẹ̀sìn tán, ẹ wá sọ ọ́ di ẹni ọ̀run àpáàdì ní ìlọ́po meji ju ẹ̀yin alára lọ.

16. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin afọ́jú tí ń fọ̀nà han eniyan. Ẹ̀ ń sọ pé, ‘Bí eniyan bá fi Tẹmpili búra, kò ṣe nǹkankan. Ṣugbọn bí eniyan bá fi wúrà tí ó wà ninu Tẹmpili búra, olúwarẹ̀ níláti mú ìbúra rẹ̀ ṣẹ.’

17. Ẹ̀yin afọ́jú òmùgọ̀ wọnyi! Èwo ni ó ṣe pataki jù! Wúrà ni tabi Tẹmpili tí a fi sọ wúrà di ohun ìyàsọ́tọ̀?

18. Ẹ tún sọ pé, ‘Bí eniyan bá fi pẹpẹ ìrúbọ búra, kò ṣe nǹkankan. Ṣugbọn bí eniyan bá fi ọrẹ tí ó wà lórí pẹpẹ ìrúbọ búra, olúwarẹ̀ níláti mú ìbúra rẹ̀ ṣẹ.’

19. Ẹ̀yin afọ́jú wọnyi! Èwo ni ó ṣe pataki jù, ọrẹ ni, tabi pẹpẹ ìrúbọ tí ó sọ ọ́ di ohun ìyàsọ́tọ̀?

20. Nítorí náà ẹni tí ó bá fi pẹpẹ ìrúbọ búra, ati pẹpẹ ati ohun gbogbo tí ó wà lórí rẹ̀ ni ó fi búra.

21. Ẹni tí ó bá fi Tẹmpili búra, ohun tí ó wà ninu rẹ̀ ati Ọlọrun tí ó ń gbé inú rẹ̀ ni ó fi búra pẹlu.

22. Ẹni tí ó bá fi ọ̀run búra, ó fi ìtẹ́ Ọlọrun ati Ọlọrun tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà búra pẹlu.

23. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn wọnyi! Ẹ̀ ń san ìdámẹ́wàá àwọn èròjà ọbẹ̀ tí wọ́n jẹ́ eléwé, nígbà tí ẹ gbàgbé àwọn ohun tí ó ṣe pataki ninu òfin: bíi ìdájọ́ òdodo, àánú, ati igbagbọ. Àwọn ohun tí ẹ̀ bá mójútó nìyí, láì gbàgbé ìdámẹ́wàá.

24. Ẹ̀yin afọ́jú tí ń fọ̀nà han eniyan! Ẹ̀ ń yọ kòkòrò tín-tìn-tín kúrò ninu ohun tí ẹ̀ ń mu, ṣugbọn ẹ̀ ń gbé ràkúnmí mì mọ́ omi yín!

Ka pipe ipin Matiu 23