Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 21:23-32 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Nígbà tí Jesu dé inú Tẹmpili, bí ó ti ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́, àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà ìlú wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Irú agbára wo ni o fi ń ṣe nǹkan wọnyi? Ta ni ó sì fún ọ ní agbára náà?”

24. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi náà yóo bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan. Tí ẹ bá dá mi lóhùn, èmi náà yóo wá sọ irú agbára tí mo fi ń ṣe nǹkan wọnyi.

25. Ìrìbọmi tí Johanu ń ṣe, báwo ló ti jẹ́: ṣé láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá ni tabi láti ọ̀dọ̀ eniyan?”Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn jiyàn, wọ́n ń wí pé, “Bí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀run ni,’ yóo bi wá pé, ‘Kí ló dé tí ẹ kò fi gbà á gbọ́?’

26. Bí a bá sì wí pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ eniyan ni,’ a bẹ̀rù àwọn eniyan, nítorí gbogbo eniyan gbà pé wolii tòótọ́ ni Johanu.”

27. Wọ́n bá dá Jesu lóhùn pé, “Àwa kò mọ̀.”Ó bá sọ fún wọn pé, “Èmi náà kò ní sọ irú àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọnyi fun yín.”

28. Ó wá bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ rò nípa èyí? Ọkunrin kan ní ọmọ meji. Ó lọ sọ́dọ̀ ekinni, ó sọ fún un pé, ‘Ọmọ, lọ ṣiṣẹ́ ninu ọgbà àjàrà mi lónìí.’

29. Ọmọ náà dá a lóhùn pé, ‘N kò ní lọ.’ Ṣugbọn lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ó ronupiwada, ó bá lọ.

30. Ọkunrin náà lọ sọ́dọ̀ ọmọ keji, ó sọ fún un bí ó ti sọ fún ekinni. Ọmọ náà dá a lóhùn pé, ‘Ó dára, mo gbọ́, Baba!’ Ṣugbọn kò lọ.

31. Ninu àwọn mejeeji, èwo ni ó ṣe ìfẹ́ baba rẹ̀?”Wọ́n ní, “Ekinni ni.”Jesu bá sọ fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé àwọn agbowó-odè ati àwọn aṣẹ́wó yóo ṣáájú yín wọ ìjọba Ọlọrun.

32. Nítorí Johanu wá sọ́dọ̀ yín ní ọ̀nà òdodo, ṣugbọn ẹ kò gbà á gbọ́. Ṣugbọn àwọn agbowó-odè ati àwọn aṣẹ́wó gbà á gbọ́. Lẹ́yìn tí ẹ rí èyí, ẹ kò ronupiwada kí ẹ gbà á gbọ́.”

Ka pipe ipin Matiu 21