Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 21:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Jerusalẹmu, tí wọ́n dé Bẹtifage ní Òkè Olifi, Jesu rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn meji lọ ṣiwaju.

2. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí ìletò tí ó wà ní ọ̀kánkán yín yìí. Bí ẹ bá ti wọ inú rẹ̀, ẹ óo rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n so mọ́lẹ̀, pẹlu ọmọ rẹ̀. Ẹ tú wọn, kí ẹ mú wọn wá fún mi.

3. Bí ẹnìkan bá bi yín ní nǹkankan, ẹ dá a lóhùn pé, ‘Oluwa nílò wọn.’ Lẹsẹkẹsẹ wọn yóo jẹ́ kí ẹ mú wọn wá.”

4. Kí ọ̀rọ̀ tí wolii nì sọ lè ṣẹ pé,

5. “Ẹ sọ fún ọdọmọbinrin, Sioni, pé,Wo ọba rẹ tí ó ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ;pẹlu ìrẹ̀lẹ̀, ó gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,ẹranko tí à ń lò láti rẹrù.”

6. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà lọ, wọ́n ṣe bí Jesu ti pàṣẹ fún wọn.

7. Wọ́n fa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ati ọmọ rẹ̀ wá, wọ́n tẹ́ aṣọ lé wọn lórí, Jesu bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gùn.

Ka pipe ipin Matiu 21