Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 20:8-18 BIBELI MIMỌ (BM)

8. “Nígbà tí ọjọ́ rọ̀, ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà náà sọ fún iranṣẹ rẹ̀ pé, ‘Pe àwọn òṣìṣẹ́, kí o fún wọn ní owó wọn, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn tí ó dé gbẹ̀yìn, títí dé ọ̀dọ̀ àwọn tí ó kọ́kọ́ dé.’

9. Nígbà tí àwọn tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní agogo marun-un ìrọ̀lẹ́ dé, wọ́n gba owó fadaka kọ̀ọ̀kan.

10. Nígbà tí àwọn tí wọn kọ́kọ́ dé ibi iṣẹ́ dé, wọ́n rò pé wọn yóo gbà ju owó fadaka kọ̀ọ̀kan lọ. Ṣugbọn owó fadaka kọ̀ọ̀kan ni àwọn náà gbà.

11. Nígbà tí wọ́n gbà á tán, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí ọlọ́gbà àjàrà náà.

12. Wọ́n ní, ‘Wakati kan péré ni àwọn yìí tí wọ́n dé kẹ́yìn ṣe; o wá san iye kan náà fún àwa ati àwọn, àwa tí a ṣe iṣẹ́ àṣelàágùn ninu oòrùn gangan!’

13. “Ṣugbọn ọlọ́gbà àjàrà náà dá ọ̀kan ninu wọn lóhùn pé, ‘Arakunrin, n kò rẹ́ ọ jẹ. Àdéhùn owó fadaka kan ni mo bá ọ ṣe.

14. Gba ohun tí ó tọ́ sí ọ kí o máa bá tìrẹ lọ; nítorí ó wù mí láti fún àwọn yìí tí wọ́n dé kẹ́yìn yìí ní ohun tí mo fún ọ.

15. Àbí n kò ní ẹ̀tọ́ láti ṣe ohun ìní mi bí mo ti fẹ́? Ṣé ò ń jowú nítorí mo ní inú rere ni?’

16. “Bẹ́ẹ̀ gan-an ni, àwọn èrò ẹ̀yìn yóo di ará iwájú, àwọn ará iwájú yóo di èrò ẹ̀yìn.”

17. Bí Jesu ti ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu, ní ọ̀nà, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila sí apá kan, níkọ̀kọ̀, ó sọ fún wọn pé,

18. “Lílọ ni à ń lọ sí Jerusalẹmu yìí o, wọn óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin lọ́wọ́, wọn óo sì dá a lẹ́bi ikú.

Ka pipe ipin Matiu 20