Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 20:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Ìjọba ọ̀run dàbí baálé ilé kan tí ó jáde ní òwúrọ̀ kutukutu láti lọ wá àwọn òṣìṣẹ́ sinu ọgbà àjàrà rẹ̀.

2. Lẹ́yìn tí ó ti gbà láti fún àwọn òṣìṣẹ́ náà ní owó fadaka kan fún iṣẹ́ ojúmọ́, ó ní kí wọ́n lọ ṣiṣẹ́ ninu ọgbà àjàrà òun.

3. Ó tún jáde lọ ní agogo mẹsan-an òwúrọ̀, ó rí àwọn mìíràn tí wọn dúró ní ọjà láìṣe nǹkankan.

4. Ó sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà ẹ lọ sinu ọgbà àjàrà mi, n óo sì fun yín ní ohun tí ó bá tọ́.’

5. Wọ́n bá lọ. Ọkunrin náà tún jáde lọ ní agogo mejila ọ̀sán ati ní agogo mẹta ọ̀sán, ó tún ṣe bákan náà.

6. Nígbà tí ó jáde ní agogo marun-un ìrọ̀lẹ́, ó rí àwọn mìíràn tí wọn dúró, ó bi wọ́n pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi dúró láti àárọ̀ láìṣe nǹkankan?’

7. Wọ́n dá a lóhùn pé, ‘Nítorí ẹnikẹ́ni kò gbà wá síṣẹ́ ni.’ Ó sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà ẹ lọ sinu ọgbà àjàrà mi.’

8. “Nígbà tí ọjọ́ rọ̀, ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà náà sọ fún iranṣẹ rẹ̀ pé, ‘Pe àwọn òṣìṣẹ́, kí o fún wọn ní owó wọn, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn tí ó dé gbẹ̀yìn, títí dé ọ̀dọ̀ àwọn tí ó kọ́kọ́ dé.’

9. Nígbà tí àwọn tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní agogo marun-un ìrọ̀lẹ́ dé, wọ́n gba owó fadaka kọ̀ọ̀kan.

10. Nígbà tí àwọn tí wọn kọ́kọ́ dé ibi iṣẹ́ dé, wọ́n rò pé wọn yóo gbà ju owó fadaka kọ̀ọ̀kan lọ. Ṣugbọn owó fadaka kọ̀ọ̀kan ni àwọn náà gbà.

11. Nígbà tí wọ́n gbà á tán, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí ọlọ́gbà àjàrà náà.

Ka pipe ipin Matiu 20