Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 12:10-23 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ. Wọ́n bi í pé, “Ṣé ó bá òfin mu láti ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi?” Kí wọ́n baà lè rí ẹ̀sùn fi kàn án ni wọ́n fi bèèrè ìbéèrè yìí.

11. Ó bá bi wọ́n báyìí pé, “Ta ni ninu yín tí yóo ní aguntan kan, bí ọ̀kan náà bá jìn sí kòtò ní Ọjọ́ Ìsinmi, tí kò ní fà á jáde?

12. Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí eniyan ti sàn ju aguntan lọ, ó tọ́ láti ṣe rere ní Ọjọ́ Ìsinmi.”

13. Ó bá sọ fún ọkunrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.”Ó bá nà án. Ọwọ́ rẹ̀ bá bọ́ sípò gẹ́gẹ́ bí ekeji.

14. Àwọn Farisi bá jáde lọ láti gbèrò nípa rẹ̀, bí wọn óo ṣe lè pa á.

15. Nígbà tí Jesu mọ̀ bẹ́ẹ̀, ó bá kúrò níbẹ̀. Ọpọlọpọ eniyan sì tẹ̀lé e, ó sì wo gbogbo wọn sàn.

16. Ó kìlọ̀ fún wọn kí wọn má ṣe polongo òun,

17. kí ọ̀rọ̀ tí wolii Aisaya sọ lè ṣẹ pé,

18. “Wo ọmọ mi tí mo yàn,àyànfẹ́ mi, ẹni tí ọkàn mi yọ̀ mọ́Èmi óo fi Ẹ̀mí mi sí i lára,yóo kéde ìdájọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu.

19. Kò ní ṣàròyé, bẹ́ẹ̀ ni kò ní pariwo,bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò ní gbọ́ ohùn rẹ̀ ní títì.

20. Kò ní dá igi tẹ́ẹ́rẹ́ tí ó tẹ̀ sí meji.Kò ní pa iná tí ó ń jó bẹ́lúbẹ́lú,títí ìdájọ́ òdodo rẹ̀ yóo fi borí.

21. Ninu orúkọ rẹ̀ ni àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu yóo ní ìrètí.”

22. Nígbà náà wọ́n mú ẹnìkan wá sọ́dọ̀ Jesu tí ó ní ẹ̀mí èṣù; ẹ̀mí èṣù yìí ti fọ́ ọ lójú, ó sì mú kí ó yadi. Jesu bá wò ó sàn; ọkunrin náà bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó sì ríran.

23. Ẹnu ya gbogbo àwọn eniyan, wọ́n ń wí pé, “Ó ha lè jẹ́ pé ọmọ Dafidi nìyí bí?”

Ka pipe ipin Matiu 12