Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 11:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn tí Jesu ti fi gbogbo ìlànà wọnyi lélẹ̀ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila tán, ó kúrò níbẹ̀ lọ sí àwọn ìlú wọn, ó ń kọ àwọn eniyan ó sì ń waasu.

2. Johanu gbọ́ ninu ẹ̀wọ̀n nípa iṣẹ́ tí Jesu ń ṣe. Ó bá rán àwọn kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n lọ bi í pé,

3. “Ṣé ìwọ ni ẹni tí ó ń bọ̀ ni, tabi kí á máa retí ẹlòmíràn?”

4. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ lọ ròyìn ohun tí ẹ ti gbọ́ ati ohun tí ẹ ti rí fún Johanu. Ẹ sọ fún un pé,

5. àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn arọ ń rìn, ara àwọn adẹ́tẹ̀ ń di mímọ́, àwọn adití ń gbọ́ràn, à ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń waasu ìyìn rere fún àwọn talaka.

6. Ẹni tí kò bá ṣiyèméjì nípa mi ṣe oríire!”

Ka pipe ipin Matiu 11