Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 7:2-17 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Wọ́n rí ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọn ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun, èyí ni pé, wọn kò wẹ ọwọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin.

3. (Nítorí pé àwọn Farisi ati gbogbo àwọn Juu yòókù kò jẹ́ jẹun láì wẹ ọwọ́ ní ọ̀nà tí òfin là sílẹ̀; wọ́n ń tẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀ wọn.

4. Bí wọn bá ti ọjà dé, wọ́n kò jẹ́ jẹun láìjẹ́ pé wọ́n kọ́kọ́ wẹ̀. Ọpọlọpọ nǹkan mìíràn ni ó ti di àṣà wọn, gẹ́gẹ́ bíi fífọ àwo ìmumi, ìkòkò ìpọnmi ati àwọn àwo kòtò onídẹ.)

5. Àwọn Farisi ati àwọn amòfin wá bi í pé, “Kí ló dé tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò fi tẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀, tí wọn ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun?”

6. Jesu wí fún wọn pé, “Òtítọ́ ni Aisaya sọ ní àtijọ́ nípa ẹ̀yin àgàbàgebè, tí ó sì kọ ọ́ báyìí pé,‘Ọlọrun wí pé: Ẹnu ni àwọn eniyan wọnyi fi ń yẹ́ mi sí,ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí mi,

7. asán ni sísìn tí wọn ń sìn mí,ìlànà eniyan ni wọ́n fi ń kọ́nibí òfin Ọlọrun.’

8. “Ẹ fi àṣẹ Ọlọrun sílẹ̀, ẹ wá dìmọ́ àṣà eniyan.”

9. Jesu tún wí fún wọn pé, “Òtítọ́ ni pé ẹ pa àṣẹ Ọlọrun tì, kí ẹ lè mú àṣẹ ìbílẹ̀ yín ṣẹ.

10. Nítorí Mose wí pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ’ ati pé, ‘Kí á pa ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ àbùkù sí baba tabi ìyá rẹ̀.’

11. Ṣugbọn ẹ̀yin wí pé, ‘Bí eniyan bá wí fún baba tabi ìyá rẹ̀ pé ohunkohun tí n bá fun yín, Kobani ni,’ (èyí ni pé ẹ̀bùn fún Ọlọrun ni),

12. ẹ ti gbà pé ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní ohunkohun í ṣe fún baba tabi ìyá rẹ̀ mọ́.

13. Ẹ fi àṣà ìbílẹ̀ yín yí ọ̀rọ̀ Ọlọrun po. Ọpọlọpọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ẹ tún ń ṣe.”

14. Ó tún pe àwọn eniyan, ó ń wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ẹ fi etí sílẹ̀, kí ọ̀rọ̀ mi ye yín.

15. Kò sí ohun kan láti òde wá tí ó wọ inú eniyan lọ tí ó lè sọ ọ́ di aláìmọ́. Ṣugbọn àwọn ohun tí ó ń jáde láti inú eniyan ni ó ń sọ ọ́ di aláìmọ́. [

16. Ẹni tí ó bá ní etí láti gbọ́ràn, kí ó gbọ́.”]

17. Nígbà tí ó kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan, tí ó wọ inú ilé lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi í ní ìtumọ̀ òwe yìí.

Ka pipe ipin Maku 7