Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 2:7-19 BIBELI MIMỌ (BM)

7. “Kí ló dé tí eléyìí fi ń sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀? Ó ń sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. Ta ni lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bíkòṣe Ọlọrun nìkan?”

8. Ṣugbọn Jesu mọ̀ ninu ara rẹ̀ pé wọ́n ń ro èrò báyìí ninu ọkàn wọn. Ó wí fún wọn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń kùn sinu?

9. Èwo ni ó rọrùn jù: Láti wí fún arọ náà pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ tabi láti wí pé, ‘Dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o máa rìn?’

10. Ṣugbọn kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ-Eniyan ní àṣẹ ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni,” ó bá wí fún arọ náà pé,

11. “Mo wí fún ọ, dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o máa lọ sí ilé rẹ.”

12. Ọkunrin náà bá dìde lẹsẹkẹsẹ, ó gbé ibùsùn rẹ̀, ó bá jáde lọ lójú gbogbo wọn. Ẹnu ya gbogbo wọn, wọ́n sì ń yin Ọlọrun, wọ́n ní, “A kò rí èyí rí.”

13. Jesu tún jáde lọ sí ẹ̀bá òkun, gbogbo àwọn eniyan ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó bá ń kọ́ wọn.

14. Bí ó ti ń lọ, ó rí Lefi ọmọ Alfeu tí ó jókòó níbi tí ó ti ń gba owó-odè. Ó wí fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.” Lefi bá dìde, ó sì tẹ̀lé e.

15. Bí Jesu ti jókòó ní ilé Lefi, ọpọlọpọ àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń bá Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jẹun, nítorí wọ́n pọ̀ tí wọn ń tẹ̀lé e.

16. Nígbà tí àwọn amòfin ninu àwọn Farisi rí i tí ó ń bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ati àwọn agbowó-odè jẹun, wọ́n bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ léèrè pé, “Kí ló dé tí ó fi ń bá àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun?”

17. Nígbà tí Jesu gbọ́, ó wí fún wọn pé, “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn bíkòṣe àwọn tí ara wọn kò dá: èmi kò wá láti pe àwọn olódodo bíkòṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”

18. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ati àwọn Farisi ń gbààwẹ̀ ní àkókò kan. Àwọn kan wá, wọ́n ń bi Jesu pé, “Kí ló dé tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn Farisi a máa gbààwẹ̀ ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tìrẹ kì í gbààwẹ̀?”

19. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ iyawo kò lè máa gbààwẹ̀ nígbà tí ọkọ iyawo wà lọ́dọ̀ wọn, níwọ̀n ìgbà tí ọkọ iyawo bá wà pẹlu wọn, wọ́n kò lè máa gbààwẹ̀.

Ka pipe ipin Maku 2