Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 12:26-34 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Nípa ti pé a óo jí àwọn òkú dìde tabi a kò ní jí wọn, ẹ kò ì tíì kà ninu Ìwé Mose, níbi ìtàn ìgbẹ́ tí iná ń jó, bí Ọlọrun ti wí fún Mose pé, ‘Èmi ni Ọlọrun Abrahamu ati Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu?’

27. Èyí ni pé Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun àwọn òkú bíkòṣe ti àwọn alààyè. Nípa ìbéèrè yìí, ẹ ti ṣìnà patapata.”

28. Amòfin kan lọ sí ọ̀dọ̀ Jesu, ó gbọ́ bí wọn tí ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀, ó wòye pé Jesu dá wọn lóhùn dáradára. Ó bá bèèrè pé, “Èwo ni ó ṣe pataki jùlọ ninu gbogbo òfin?”

29. Jesu dáhùn pé, “Èyí tí ó ṣe pataki jùlọ nìyí, ‘Gbọ́, Israẹli, Oluwa Ọlọrun wa nìkan ni Oluwa.

30. Kí ìwọ fẹ́ràn Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati pẹlu gbogbo ẹ̀mí rẹ ati pẹlu gbogbo iyè inú rẹ, ati pẹlu gbogbo agbára rẹ.’

31. Èyí tí ó ṣìkejì ni pé, ‘Kí ìwọ fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ bí o ti fẹ́ràn ara rẹ.’ Kò sí òfin mìíràn tí ó tóbi ju èyí lọ.”

32. Amòfin náà wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ gan-an ni, Olùkọ́ni. Òtítọ́ ni o sọ pé, ‘Ọlọrun kan ni ó wà. Kò sí òmíràn lẹ́yìn rẹ̀’;

33. ati pé, ‘Kí á fẹ́ràn ẹnìkejì wa bí a ti fẹ́ràn ara wa’ tayọ gbogbo ẹbọ sísun ati ẹbọ yòókù.”

34. Nígbà náà ni Jesu ṣe akiyesi pé ó fi òye sọ̀rọ̀, ó wí fún un pé, “Ìwọ kò jìnnà sí ìjọba Ọlọrun.”Kò sì sí ẹnìkan tí ó ní ìgboyà láti tún bi í ní ìbéèrè kankan mọ́.

Ka pipe ipin Maku 12