Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 11:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Jerusalẹmu, nítòsí Bẹtifage ati Bẹtani, ní orí Òkè Olifi, ó rán meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀;

2. ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí abúlé tí ẹ̀ ń wò ní ọ̀kánkán yìí, bí ẹ bá ti wọ inú rẹ̀, ẹ óo rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí ẹnikẹ́ni kò gùn rí, tí wọ́n so mọ́ èèkàn, ẹ tú u, kí ẹ fà á wá.

3. Bí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ̀ ń tú u?’ Kí ẹ dáhùn pé, ‘Oluwa fẹ́ lò ó ni, lẹsẹkẹsẹ tí ó bá ti lò ó tán yóo dá a pada sibẹ.’ ”

4. Wọ́n lọ, wọ́n rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tí a so ní ẹnu ìlẹ̀kùn lóde, lẹ́bàá títì, wọ́n bá tú u.

5. Àwọn kan tí wọ́n ti jókòó níbẹ̀ bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ̀ ń tú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́?”

6. Wọ́n bá dá wọn lóhùn gẹ́gẹ́ bí Jesu ti wí fún wọn. Àwọn eniyan náà sì yọ̀ǹda fún wọn.

7. Wọ́n bá fa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà wá sí ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n tẹ́ aṣọ wọn sí orí rẹ̀, Jesu bá gùn un.

8. Ọpọlọpọ eniyan tẹ́ aṣọ wọn sí ọ̀nà, àwọn mìíràn tẹ́ ẹ̀ka igi tí wọ́n ya ní pápá.

9. Àwọn tí ó ń lọ ní iwájú ati àwọn tí ó ń bọ̀ ní ẹ̀yìn ń kígbe pé,“Hosana!Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ ní orúkọ Oluwa.

10. Ibukun ni ìjọba tí ń bọ̀,ìjọba Dafidi baba ńlá wa.Hosana ní òkè ọ̀run!”

11. Nígbà tí ó wọ Jerusalẹmu, ó wọ àgbàlá Tẹmpili, ó wo ohun gbogbo yíká. Nítorí ọjọ́ ti lọ, ó jáde lọ sí Bẹtani pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila.

Ka pipe ipin Maku 11