Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 1:16-29 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Bí Jesu ti ń rìn lọ lẹ́bàá òkun Galili, ó rí Simoni ati Anderu arakunrin rẹ̀ tí wọn ń da àwọ̀n sinu òkun, nítorí apẹja ni wọ́n.

17. Jesu bá wí fún wọn pé, “Ẹ wá máa tẹ̀lé mi, èmi yóo sọ yín di ẹni tí ó ń fa eniyan bí a ti ń dẹ ẹja ninu omi.”

18. Lẹ́sẹ̀ kan náà wọ́n bá fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n ń tẹ̀lé e.

19. Bí ó ti rìn siwaju díẹ̀ sí i, ó rí Jakọbu ọmọ Sebede ati Johanu arakunrin rẹ̀ ninu ọkọ̀, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe.

20. Bí Jesu ti rí wọn, ó pè wọ́n. Wọ́n bá fi Sebede baba wọn sílẹ̀ ninu ọkọ̀ pẹlu àwọn alágbàṣe, wọ́n ń tẹ̀lé e.

21. Wọ́n lọ sí Kapanaumu. Ní Ọjọ́ Ìsinmi àwọn Juu, Jesu lọ sí ilé ìpàdé, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn eniyan.

22. Ẹnu ya àwọn tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀, nítorí ó ń kọ́ wọn bí ẹni tí ó ní àṣẹ, yàtọ̀ sí bí àwọn amòfin ṣe ń kọ́ wọn.

23. Ọkunrin kan wà ninu ilé ìpàdé náà tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ó bá kígbe tòò, ó ní,

24. “Kí ni ó pa tàwa-tìrẹ pọ̀, Jesu ará Nasarẹti? Ṣé o dé láti pa wá run ni? Mo mọ ẹni tí o jẹ́. Ẹni Mímọ́ Ọlọrun ni ọ́.”

25. Jesu bá bá a wí, ó ní, “Pa ẹnu mọ́, kí o jáde kúrò ninu ọkunrin yìí.”

26. Ẹ̀mí èṣù náà bá gbo ọkunrin náà jìgìjìgì, ó kígbe tòò, ó sì jáde kúrò ninu ọkunrin náà.

27. Kẹ́kẹ́ bá pamọ́ gbogbo àwọn eniyan lẹ́nu tóbẹ́ẹ̀ tí wọn ń wí láàrin ara wọn pé, “Kí ni èyí? Ẹ̀kọ́ titun ni! Pẹlu àṣẹ ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí èṣù wí, wọ́n sì gbọ́ràn sí i lẹ́nu.”

28. Òkìkí Jesu wá kan ká gbogbo ìgbèríko Galili.

29. Bí wọ́n ti jáde kúrò ninu ilé ìpàdé, Jesu pẹlu Jakọbu ati Johanu lọ sí ilé Simoni ati Anderu.

Ka pipe ipin Maku 1