Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 5:3-21 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Jesu bá wọ inú ọ̀kan ninu àwọn ọkọ̀ náà tí ó jẹ́ ti Simoni, ó ní kí wọ́n tù ú kúrò létí òkun díẹ̀. Ni ó bá jókòó ninu ọkọ̀, ó ń kọ́ àwọn eniyan.

4. Nígbà tí ó parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, ó sọ fún Simoni pé, “Tu ọkọ̀ lọ sí ibú, kí o da àwọ̀n sí omi kí ó lè pa ẹja.”

5. Simoni dáhùn pé, “Alàgbà, gbogbo òru ni a fi ṣiṣẹ́ láì rí ohunkohun pa, ṣugbọn nítorí ọ̀rọ̀ rẹ, n óo da àwọ̀n sí omi.”

6. Nígbà tí ó dà á sinu omi, ẹja tí ó kó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọ̀n fẹ́ ya.

7. Wọ́n bá ṣe àmì sí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tí ó wà ninu ọkọ̀ keji pé kí wọ́n wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n dé, wọ́n da ẹja kún inú ọkọ̀ mejeeji, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi fẹ́ rì.

8. Nígbà tí Simoni Peteru rí i, ó kúnlẹ̀ níwájú Jesu, ó ní “Kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí, Oluwa.”

9. Nítorí ẹnu yà á ati gbogbo àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fún ọpọlọpọ ẹja tí wọ́n rí pa.

10. Ẹnu ya Jakọbu náà ati Johanu, àwọn ọmọ Sebede, tí wọ́n jẹ́ ẹlẹgbẹ́ Simoni. Jesu wá sọ fún Peteru pé, “Má bẹ̀rù. Láti ìgbà yìí lọ eniyan ni ìwọ yóo máa mú wá.”

11. Nígbà tí wọ́n tu ọkọ̀ dé èbúté, wọ́n fi ohun gbogbo sílẹ̀, wọ́n ń tẹ̀lé e.

12. Ní àkókò kan nígbà tí Jesu wà ninu ìlú kan, ọkunrin kan tí ẹ̀tẹ̀ bò ní gbogbo ara rí i. Ó bá wá dojúbolẹ̀, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Alàgbà, bí o bá fẹ́, o lè sọ ara mi di mímọ́.”

13. Jesu bá na ọwọ́, ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́ kí ara rẹ di mímọ́.” Lẹsẹkẹsẹ àrùn ẹ̀tẹ̀ náà fi í sílẹ̀.

14. Jesu bá kìlọ̀ fún un pé, “Má ṣe sọ fún ẹnikẹ́ni, ṣugbọn lọ fi ara rẹ han alufaa, kí o ṣe ìrúbọ fún ìsọdi-mímọ́ rẹ, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ. Èyí yóo jẹ́ ẹ̀rí fún wọn pé ara rẹ ti dá.”

15. Ṣugbọn ńṣe ni ìròyìn rẹ̀ túbọ̀ ń tàn kálẹ̀. Ọ̀pọ̀ eniyan wá ń péjọ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ati kí ó lè wò wọ́n sàn kúrò ninu àìlera wọn.

16. Ṣugbọn aṣálẹ̀ ni ó máa ń lọ láti dá gbadura.

17. Ní ọjọ́ kan bí Jesu ti ń kọ́ àwọn eniyan, àwọn Farisi ati àwọn amòfin jókòó níbẹ̀. Wọ́n wá láti gbogbo ìletò Galili ati ti Judia ati láti Jerusalẹmu. Agbára Oluwa wà pẹlu Jesu láti fi ṣe ìwòsàn.

18. Àwọn ẹnìkan gbé ọkunrin arọ kan wá tí ó dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn rẹ̀. Wọ́n ń wá ọ̀nà láti gbé e dé iwájú Jesu.

19. Nígbà tí wọn kò rí ọ̀nà gbé e dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀ eniyan, wọ́n gbé e gun orí òrùlé. Wọ́n bá dá òrùlé lu kí wọ́n fi lè gbé arọ náà pẹlu ibùsùn rẹ̀ sí ààrin àwọn eniyan níwájú Jesu.

20. Nígbà tí Jesu rí igbagbọ wọn, ó ní, “Arakunrin, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”

21. Àwọn amòfin ati àwọn Farisi bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn sọ pé, “Ta ni eléyìí tí ó ń sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun báyìí? Ta ni lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan lẹ́yìn Ọlọrun nìkan ṣoṣo?”

Ka pipe ipin Luku 5