Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 4:9-21 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Èṣù tún mú un lọ sí Jerusalẹmu. Ó gbé e ka téńté òrùlé Tẹmpili. Ó ní, “Bí ó bá jẹ́ pé Ọmọ Ọlọrun ni ọ́ nítòótọ́, bẹ́ sílẹ̀ láti ìhín.

10. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Yóo pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀ nítorí rẹ pé kí wọn pa ọ́ mọ́.’

11. Ati pé, ‘Kí wọn tẹ́wọ́ gbà ọ́ kí o má baà fi ẹsẹ̀ gbún òkúta.’ ”

12. Jesu dá a lóhùn pé, “A ti sọ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò.’ ”

13. Nígbà tí Satani parí gbogbo ìdánwò yìí, ó fi Jesu sílẹ̀ títí di àkókò tí ó bá tún wọ̀.

14. Jesu pada sí Galili pẹlu agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Òkìkí rẹ̀ kàn ká gbogbo ìgbèríko.

15. Ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu àwọn ilé ìpàdé wọn. Gbogbo eniyan sì ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní rere.

16. Ó wá dé Nasarẹti, ìlú tí wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, nígbà tí ó di ọjọ́ ìsinmi, ó lọ sí ilé ìpàdé. Ó bá dìde láti ka Ìwé Mímọ́.

17. Wọ́n fún un ní ìwé wolii Aisaya. Nígbà tí ó ṣí i, ó rí ibi tí a gbé kọ ọ́ pé,

18. “Ẹ̀mí Oluwa wà pẹlu minítorí ó ti fi òróró yàn míláti waasu ìyìn rere fún àwọn talaka.Ó rán mi láti waasu ìtúsílẹ̀fún àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn,ati láti mú kí àwọn afọ́jú ríran;láti jẹ́ kí àwọn tí a ni lára lọ ní alaafia,

19. ati láti waasu ọdún tí Oluwa yóo gba àwọn eniyan rẹ̀ là.”

20. Ó bá pa ìwé náà dé, ó fi í fún olùtọ́jú ilé ìpàdé, ó bá jókòó. Gbogbo àwọn eniyan tí ó wà ninu ilé ìpàdé tẹjú mọ́ ọn;

21. ó bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún wọn pé, “Lónìí ni àkọsílẹ̀ yìí ṣẹ ní ojú yín.”

Ka pipe ipin Luku 4