Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 3:6-22 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Gbogbo eniyan ni yóo rí ìgbàlà Ọlọrun.’ ”

7. Johanu ń sọ fún àwọn eniyan tí ó jáde lọ ṣe ìrìbọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fun yín láti sá fún ibinu tí ń bọ̀?

8. Ẹ fihàn ninu ìwà yín pé ẹ ti ronupiwada. Ẹ má bẹ̀rẹ̀ láti máa rò ninu ara yín pé, ‘A ní Abrahamu ní baba.’ Nítorí mò ń sọ fun yín pé Ọlọrun lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu láti inú òkúta wọnyi.

9. A sì ti fi àáké lé gbòǹgbò igi báyìí. Nítorí náà, igikígi tí kò bá máa so èso rere ni a óo gé lulẹ̀, tí a óo sì fi dáná.”

10. Àwọn eniyan wá bi í pé, “Kí ni kí a wá ṣe?”

11. Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹni tí ó bá ní dàńṣíkí meji, kí ó fún ẹni tí kò ní lọ́kan. Ẹni tí ó bá ní oúnjẹ níláti ṣe bákan náà.”

12. Àwọn agbowó-odè náà wá láti ṣe ìrìbọmi. Wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, kí ni kí a ṣe?”

13. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe gbà ju iye tí ó tọ́ lọ.”

14. Àwọn ọmọ-ogun náà ń bi í pé, “Àwa náà ńkọ́, kí ni kí a ṣe?”Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe dẹ́rù ba ẹnikẹ́ni láti lọ́ wọn lọ́wọ́ gbà, Ẹ má ṣe fi ẹ̀sùn èké kan ẹnikẹ́ni. Ẹ jẹ́ kí owó oṣù yín to yín.”

15. Àwọn eniyan ń retí, gbogbo wọn ń rò ninu ọkàn wọn bí Johanu bá ni Mesaya.

16. Johanu sọ fún gbogbo eniyan pé, “Omi ni èmi fi ń ṣe ìwẹ̀mọ́ fun yín, ṣugbọn ẹni tí ó jù mí lọ ń bọ̀. Èmi kò tó ẹni tíí tú okùn bàtà rẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ ati iná ni yóo fi wẹ̀ yín mọ́.

17. Àtẹ ìfẹ́kà ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀ tí yóo fi fẹ́ ọkà inú oko rẹ̀; yóo kó ọkà rẹ̀ sinu abà, yóo sì sun fùlùfúlù ninu iná àjóòkú.”

18. Ní ọ̀nà yìí ati ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà mìíràn, Johanu ń gba àwọn eniyan níyànjú, ó sì ń sọ̀rọ̀ ìyìn rere fún wọn.

19. Ní àkókò kan, Johanu bá Hẹrọdu baálẹ̀ wí nítorí ọ̀ràn Hẹrọdiasi, iyawo Filipi, arakunrin rẹ̀, tí Hẹrọdu gbà. Ó tún bá a wí fún gbogbo nǹkan burúkú mìíràn tí ó ṣe.

20. Hẹrọdu wá tún fi ti Johanu tí ó sọ sẹ́wọ̀n kún gbogbo ìwà burúkú rẹ̀.

21. Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan ń ṣe ìrìbọmi, Jesu náà ṣe ìrìbọmi. Lẹ́yìn náà, bí ó ti ń gbadura, ọ̀run ṣí sílẹ̀.

22. Ẹ̀mí Mímọ́ fò wálẹ̀ bí àdàbà ó bà lé e lórí. Ohùn kan wá fọ̀ láti ọ̀run pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi; inú mi dùn sí ọ gidigidi.”

Ka pipe ipin Luku 3