Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 3:15-28 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Àwọn eniyan ń retí, gbogbo wọn ń rò ninu ọkàn wọn bí Johanu bá ni Mesaya.

16. Johanu sọ fún gbogbo eniyan pé, “Omi ni èmi fi ń ṣe ìwẹ̀mọ́ fun yín, ṣugbọn ẹni tí ó jù mí lọ ń bọ̀. Èmi kò tó ẹni tíí tú okùn bàtà rẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ ati iná ni yóo fi wẹ̀ yín mọ́.

17. Àtẹ ìfẹ́kà ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀ tí yóo fi fẹ́ ọkà inú oko rẹ̀; yóo kó ọkà rẹ̀ sinu abà, yóo sì sun fùlùfúlù ninu iná àjóòkú.”

18. Ní ọ̀nà yìí ati ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà mìíràn, Johanu ń gba àwọn eniyan níyànjú, ó sì ń sọ̀rọ̀ ìyìn rere fún wọn.

19. Ní àkókò kan, Johanu bá Hẹrọdu baálẹ̀ wí nítorí ọ̀ràn Hẹrọdiasi, iyawo Filipi, arakunrin rẹ̀, tí Hẹrọdu gbà. Ó tún bá a wí fún gbogbo nǹkan burúkú mìíràn tí ó ṣe.

20. Hẹrọdu wá tún fi ti Johanu tí ó sọ sẹ́wọ̀n kún gbogbo ìwà burúkú rẹ̀.

21. Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan ń ṣe ìrìbọmi, Jesu náà ṣe ìrìbọmi. Lẹ́yìn náà, bí ó ti ń gbadura, ọ̀run ṣí sílẹ̀.

22. Ẹ̀mí Mímọ́ fò wálẹ̀ bí àdàbà ó bà lé e lórí. Ohùn kan wá fọ̀ láti ọ̀run pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi; inú mi dùn sí ọ gidigidi.”

23. Jesu tó ẹni ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀. Ọmọ Josẹfu ni àwọn eniyan mọ̀ ọ́n sí. Josẹfu jẹ́ ọmọ Eli,

24. ọmọ Matati, ọmọ Lefi, ọmọ Meliki, ọmọ Janai, ọmọ Josẹfu,

25. ọmọ Matatiya, ọmọ Amosi, ọmọ Nahumu, ọmọ Esili, ọmọ Nagai,

26. ọmọ Maati, ọmọ Matatiya, ọmọ Semehin, ọmọ Joseki, ọmọ Joda,

27. ọmọ Johana, ọmọ Resa, ọmọ Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, ọmọ Neri,

28. ọmọ Meliki, ọmọ Adi, ọmọ Kosamu, ọmọ Elimadamu, ọmọ Eri,

Ka pipe ipin Luku 3