Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 24:9-21 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Wọ́n bá kúrò ní ibojì náà, wọ́n pada lọ sọ gbogbo nǹkan tí wọ́n rí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọkanla ati gbogbo àwọn yòókù.

10. Maria Magidaleni, ati Joana, ati Maria ìyá Jakọbu ati gbogbo àwọn yòókù tí ó bá wọn lọ, ni wọ́n sọ nǹkan wọnyi fún àwọn aposteli.

11. Ṣugbọn bíi ìsọkúsọ ni gbogbo ọ̀rọ̀ yìí rí létí wọn. Wọn kò gba ohun tí àwọn obinrin náà sọ gbọ́. [

12. Ṣugbọn Peteru dìde, ó sáré lọ sí ibojì náà. Nígbà tí ó yọjú wo inú rẹ̀, aṣọ funfun tí wọ́n fi wé òkú nìkan ni ó rí. Ó bá pada sí ilé, ẹnu yà á sí ohun tí ó ṣẹlẹ̀.]

13. Ní ọjọ́ kan náà, àwọn meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ń lọ sí abúlé kan tí ó ń jẹ́ Imausi. Ó tó bí ibùsọ̀ meje sí Jerusalẹmu.

14. Wọ́n ń bá ara wọn jíròrò lórí gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.

15. Bí wọ́n ti ń bá ara wọn jíròrò, tí wọn ń bá ara wọn jiyàn, Jesu alára bá súnmọ́ wọn, ó ń bá wọn rìn lọ.

16. Ṣugbọn ó dàbí ẹni pé a dì wọ́n lójú, wọn kò mọ̀ pé òun ni.

17. Ó bá bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ̀ ń bá ara yín sọ bí ẹ ti ń rìn bọ̀? Kí ló dé tí ojú yín fi rẹ̀wẹ̀sì bẹ́ẹ̀?”

18. Ọ̀kan ninu wọn tí ń jẹ́ Kilopasi dá a lóhùn pé, “Ṣé àlejò ni ọ́ ní Jerusalẹmu ni, tí o kò fi mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ ní ààrin bí ọjọ́ mélòó kan yìí?”

19. Jesu bá bi í pé, “Bíi kí ni?”Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Jesu ará Nasarẹti ni. Wolii ni, iṣẹ́ rẹ̀ ati ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì fi agbára hàn níwájú Ọlọrun ati gbogbo eniyan.

20. Ṣugbọn àwọn olórí alufaa ati àwọn ìjòyè wa fà á fún ìdájọ́ ikú, wọ́n bá kàn án mọ́ agbelebu.

21. Òun ní àwa ti ń retí pé yóo fún Israẹli ní òmìnira. Ati pé ju gbogbo rẹ̀ lọ, ọjọ́ kẹta nìyí tí gbogbo rẹ̀ ti ṣẹlẹ̀.

Ka pipe ipin Luku 24