Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 24:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní kutukutu òwúrọ̀ ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, wọ́n wá sí ibojì, wọ́n mú òróró olóòórùn dídùn tí wọ́n ti tọ́jú lọ́wọ́.

2. Wọ́n rí i pé wọ́n ti yí òkúta kúrò ní ẹnu ibojì.

3. Nígbà tí wọ́n wọ inú ibojì, wọ́n kò rí òkú Jesu Oluwa.

4. Bí wọ́n ti dúró tí wọn kò mọ ohun tí wọn yóo ṣe, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkunrin meji kan bá yọ sí wọn, wọ́n wọ aṣọ dídán.

5. Ẹ̀rù ba àwọn obinrin náà, wọ́n bá dojúbolẹ̀. Àwọn ọkunrin náà wá bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń wá alààyè láàrin àwọn òkú?

6. Kò sí níhìn-ín; ó ti jí dìde. Ẹ ranti bí ó tí sọ fun yín nígbà tí ó wà ní Galili pé,

7. ‘Dandan ni kí á fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn eniyan burúkú lọ́wọ́, kí wọ́n kàn án mọ́ agbelebu, ati pé kí ó jí dìde ní ọjọ́ kẹta.’ ”

8. Wọ́n wá ranti ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Ka pipe ipin Luku 24