Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 22:37-57 BIBELI MIMỌ (BM)

37. Nítorí mo wí fun yín pé ohun gbogbo tí a ti kọ sílẹ̀ nípa mi níláti ṣẹ, pé, ‘A kà á kún àwọn arúfin.’ Ohun tí a sọ nípa mi yóo ṣẹ.”

38. Wọ́n sọ fún un pé, “Oluwa, wò ó! Idà meji nìyí.”Ó sọ fún wọn pé, “Ó tó!”

39. Jesu bá jáde lọ sórí Òkè Olifi, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tẹ̀lé e.

40. Nígbà tí ó dé ibẹ̀ ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ máa gbadura kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò.”

41. Ó bá kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó lọ siwaju díẹ̀ sí i. Ó kúnlẹ̀, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí gbadura.

42. Ó ní, “Baba, bí o bá fẹ́, mú kí ife kíkorò yìí fò mí ru. Ṣugbọn ìfẹ́ tèmi kọ́, ìfẹ́ tìrẹ ni kí ó ṣẹ.” [

43. Angẹli kan yọ sí i láti ọ̀run láti ràn án lọ́wọ́. Pẹlu ọkàn wúwo, ó túbọ̀ gbadura gidigidi.

44. Òógùn ojú rẹ̀ dàbí kí ẹ̀jẹ̀ máa kán bọ́ sílẹ̀.]

45. Ó bá dìde lórí adura, ó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rí wọn tí wọn ń sùn nítorí àárẹ̀ ìbànújẹ́.

46. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ̀ ń sùn ni! Ẹ dìde kí ẹ máa gbadura, kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò.”

47. Bí Jesu ti ń sọ̀rọ̀ ni àwọn eniyan bá dé. Judasi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, ni ó ṣiwaju wọn. Ó bá súnmọ́ Jesu, ó fi ẹnu kò ó ní ẹ̀rẹ̀kẹ́.

48. Jesu sọ fún un pé, “Judasi! O sì fi ẹnu ko Ọmọ-Eniyan ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ láti fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́?”

49. Nígbà tí àwọn tí ó wà pẹlu Jesu rí i, wọ́n ní, “Oluwa, ṣé kí á fa idà yọ?”

50. Ni ọ̀kan ninu wọ́n bá ṣá ẹrú olórí alufaa kan, ó bá gé e ní etí ọ̀tún.

51. Ṣugbọn Jesu sọ pé, “Ẹ fi wọ́n sílẹ̀.” Ó bá fọwọ́ kan etí ẹrú náà, etí náà sì san.

52. Ó wá sọ fún àwọn olórí alufaa, ati àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili ati àwọn àgbà tí wọ́n wá mú un pé, “Ọlọ́ṣà ni ẹ pè mí ni, tí ẹ fi kó idà ati kùmọ̀ wá?

53. Ṣebí ojoojumọ ni mo wà pẹlu yín ninu Tẹmpili. Ẹ kò ṣe fọwọ́ kàn mí? Ṣugbọn àkókò yín ati ti aláṣẹ òkùnkùn nìyí.”

54. Wọ́n bá mú Jesu, wọ́n fà á lọ sí ilé Olórí Alufaa. Ṣugbọn Peteru ń tẹ̀lé wọn lókèèrè.

55. Àwọn kan dá iná sáàrin agbo-ilé, wọ́n jókòó yí i ká, Peteru náà wà láàrin wọn.

56. Ọmọdebinrin kan wá rí i, ó tẹjú mọ́ ọn, ó ní, “Ọkunrin yìí wà pẹlu Jesu.”

57. Ṣugbọn Peteru sẹ́, ó ní, “N kò tilẹ̀ mọ ọkunrin yìí!”

Ka pipe ipin Luku 22